Obìnrin kan fa ìwé ìrìnnà ọkọ rẹ̀ ya, ariwo sọ, ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè gbé ìgbésẹ̀

Iwe irinna Naijiria
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ariwo sọ lori ayelujara nipa obinrin kan to fa iwe irinna ọkọ rẹ silẹ okeere ya pẹrẹpẹrẹ.

Isẹlẹ naa lo waye ni papakọ ofurufu Murtala Mohammed to wa nipinlẹ Eko, ti ẹrọ ayaworan to wa nibẹ si ka igbesẹ obinrin naa silẹ, bo se n ya iwe irinna ọkọ rẹ naa.

Obinrin ọhun, Favour Igiebor, ninu fọnran kan to fi sori ayelujara ti sọrọ gbe ara rẹ lẹyin nipa ohun to ṣokunfa idi to fi fa iwe irinna ọkọ rẹ naa ya.

Isẹlẹ naa si lo mu ki ọpọ eeyan naa fi ẹnu tẹmpẹlu iwa ti obinrin naa hu eyi ti wọn lo ku diẹ kaato.

Ninu fọnran oniṣẹju mẹfa ọhun ni Favour si ti salaye idi to fi se bẹẹ.

"Mo ti sọ fun ọkọ mi saaju pe o seese ko ma pada kuro ni Naijiria, o ro pe ere ni mo n se"

Ninu alaye rẹ, Favour Igiebor ni, gbogbo awọn to n sọ oriṣiriṣi lori ohun to ṣẹlẹ ko mọ bi nnkan ṣe n lọ ninu idile oun.

O jẹ ko di mimọ pe, ọkọ oun mọ nipa nnkan to n ṣe fun oun, to si tun ra foonu olowo nla fun oun lati fi tu oun ninu, ṣugbọn to ni oun ṣi gbe ọrọ naa sara.

Favour tẹsiwaju ninu fọnran ọhun pe nnkan to ṣẹlẹ naa, oun ti n sọ fun ọkọ oun tipẹ, ṣugbọn o ro pe awada lasan ni oun n ṣe.

“Naijiria ti a n lọ yii, mo sọ fun pe mi o lero pe o maa pada, ṣugbọn bi ere, bi awada ni oun n fi ṣe.”

Ninu fọnran oniṣẹju marun-un to tun gbe sita lẹyin wakati mẹfa, Favour wa rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ aṣọbode lori bo ṣe fa iwe irinna ọkọ rẹ ya.

Ṣugbọn ọkọ naa tun ti wa gbe fọnran tiẹ naa sita, to si ni oun to n ṣẹlẹ laaarin oun ati iyawo oun, ko to nnkan to yẹ ko wọ ori ayelujara.

Ọkọ atiyawo naa ni wọn jọ n lo oju opo kan naa gẹgẹ bii mọlẹbi pẹlu awọn ọmọ wọn mẹta.

Igbesẹ wo ni ileesẹ asọbode n gbe nipa isẹlẹ yii?

Nibayii, Ileeṣẹ aṣọbode ni Naijiria ti sọrọ sita lori igbesẹ ti Favour Igiebor gbe lati fa iwe irinna ọkọ rẹ ya lojutaye.

Ninu atẹjade kan to fisita, ileesẹ asọbode ni bẹrẹ iwadii ti bẹrẹ lori iwa sise abuku silẹ Naijiria naa.

Ninu atẹjade ọhun, agbẹnusọ ileeṣẹ aṣọbode, Kenneth Udo sọ pe ọga awọn patapata ti paṣẹ ki wọn pe obinrin naa lati fi ọrọ wa a lẹnu wo.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ aṣọbode ṣe sọ, bi wọn ba ṣawari wi pe obinrin naa jẹbi ẹsun fifa iwe irinna ọkọ rẹ ya, iwa rẹ yoo tako abala kẹwaa, ipin keji (section 10 (b)) ninu iwe ofin aṣọbode ti ọdun 2015, ti yoo si gba ijiya rẹ ni abala kẹwaa, ipin kẹjọ (section 10 (h)) ninu iwe ofin ọhun.

Atẹjade ti ileesẹ asọbode fi sita

Oríṣun àwòrán, @nigimmigration

Ijiya wo lo wa fun ọmọ orilẹede yii to ba fa iwe irinna Naijiria ya?

Udo sọ pe “Ojuṣe ileeṣẹ Nigeria Immigration Service ni lati daabobo awọn ohun ti ofin aṣọbode sọ ni ifẹ si eto aabo apapọ, ati lati daabo bo iyi awọn ohun elo ofin orileede.”

Abala kinni, ipin kinni iwe irinna (Miscellaneous Provisions) sọ pe iwa ọdaran ni lati ṣe ohun ti ko ba ofin mu pẹlu iwe irinna.

“(c)pipaarọ lai bofin mu, ṣiṣe ohun ti ko ba ofin mu, tabi ayipada rampẹ si iwe irinna tabi awọn abala inu rẹ” tabi “(I) igbiyanju lati gbimọ papọ lati gba iwe irinna lọna ti ko ba ofin mu.”

Abala keji sọ pe “Ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun yii labẹ ipin keji (b) titi de ipin kẹsan (i) ni abala kinni iwe ofin yii, jẹbi lati fi ẹwọn ọdun kan gbako gbara.”