Ohun tó kù fún mí ni láti ṣiṣẹ́ sin ilẹ̀ Ibadan, àwòkọ́ṣe ńlá ni ohun tó wáyé lónìí jẹ́ -Ladoja

Aworan Oba Adewolu Ladoja ati igbakeji Gomina ipinlẹ Oyo, Bayo Lawal
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni ibi akanṣe eto ifinijoye to waye lọjọ Aje ni aafin Olubadan ile Ibadan to n bẹ ni agbegbe Oke Arẹmọ ni Oloye Agba Rashidi Ladoja ti gba Ade Ọba.

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Akinloye Owolabi Olakulehin, Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Lawal, Arabo Oluawo ilẹ Ibadan, Odegbola Ifalere, awọn Baale ati Mogaji ilẹ Ibadan awọn Oloye ni ọkanojọkan ko gbẹyin ni ibi eto naa.

Igbakeji Gomina Oyo, Amofin Bayo Lawal ni awokọse nla ni ohun to n waye niluu Ibadan nipa Ọba jijẹ jẹ fun ọpọ ilẹ Yoruba.

Lawal, ẹni to n dele fun Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lo sọ eyi nigba to soju Gomina nibi ayẹyẹ igba-ade Oloye Ladoja ni aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan.

Igbakeji Gomina ni igbagbọ ọpọ eeyan ni pe ilu ibadan n toro, gbogbo ilẹ Kaarọ oo-jiire lo n toro.

“Inu mi dun pe gbogbo awuyewuye ti dopin, ti a si ti se ara wa ni ọkan.

“Mo ki gbogbo ọmọ Ibadan ku orire, pe gbogbo awuyewuye ti dopin, ti ara ita ko si ri aye lati dasi aarin awọn agba ilu.

“Awokọse nla ni eyi jẹ fun awọn ilẹ Kaarọ-oo-jiire. Mo ki gbogbo awọn ori alade to jẹ ki eyi wa siu imusẹ"

Aworan Oba Adewolu Ladoja

"Ohun ti o ku fun mi lati maa ṣe lọjọ ogbo ni ki n sin ilẹ Ibadan"

Ninu ọrọ ti o sọ lẹyin ti o gba Ade gẹgẹ bii Ọba Ojuopo nilẹ Ibadan, Ọba Ladọja dupẹ lọwọ Ọba Ọlakulẹhin ati gbogbo ọmọ ilẹ Ibadan fun ipa ti wọn ko lati jẹ ki eto naa di nnkan aṣeyọri.

Ọba Ladọja ni "awọn eeyan ti wọn ko mọ nipa ihuwasi awọn ọmọ ilẹ Ibadan lo n pariwo wi pe ọrọ oye jijẹ yoo da wahala silẹ nilẹ Ibadan."

O ni gbogbo awọn Ọba to wa loju Opo lọ jẹ alamọran ati iranṣẹ fun Olubadan ilẹ Ibadan, pẹlu alaye pe Ọba kan ṣoṣo ni olori gbogbo Ọba to n bẹ nilẹ Ibadan, oun naa si ni Ọba Akinloye Owolabi Olakulehin.

Ọba Ladọja ṣe alaye wi pe ohun ti o ku fun oun lati maa ṣe lọjọ ogbo ni ki oun maa sin ilẹ Ibadan.

Gbogbo awọn Ọba yii lọ jẹ alamọran ati iranṣẹ fun Olubadan ilẹ Ibadan

Ọba Ladoja tẹsiwaju pe ko si bi awọn ọmọ ilẹ Ibadan ṣe leri mọ ara awọn to nita gbangban, bi wọn ba ti jọ wọ iyẹwu jade, gbogbo nnkan to fa ija ni yoo di ohun igbagbe.

Ladọja ni iredi ti oun ko fi gba Ade tẹlẹri ni pe ko si ẹni kan to dahun ibeere ti oun n beere wi pe, "Ade oye wo ni mo fẹ gba?".

Ṣugbọn ni bayii ti adahun ti wa si ibeere naa wi pe Ade Ọba Ojuopo ni yoo jẹ, ni eto ifinijoye naa fi waye lonii.

Ọba Ladọja tẹsiwaju wi pe gbogbo awọn agba oye ilẹ Ibadan lo ni ẹtọ lati jẹ oye Ọba Ojuopo, bẹrẹ lati ori Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Ẹkẹrin Olubadan, titi to fi de ori Aṣipa.

O ni dara ki a sin ilẹ Naijiria ṣugbọn ilẹ Ibadan ni akọkọ lọkan oun.

O gba adura fun itẹsiwaju ati idagbasoke ilẹ Ibadan ni a apapọ.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, Ladoja yoo gba adé idẹ n'Íbàdàn lónìí

Oloye Rasidi Ladoja

Oríṣun àwòrán, Others

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin laarọ pe gbogbo eto lo ti to fun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Akinloye Olakulehin lati de ade idẹ fun Otun Olubadan, Sẹnetọ Rashidi Adewolu Ladoja.

Oni ti i ṣe ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii ni ayẹyẹ igbade naa yoo waye ni aafin Olubadan to wa lagbegbe Oke Aremo, niluu Ibadan.

Ọsẹ to kọja ni Gomina Seyi Makinde lọ sile Sẹnetọ Ladoja, ti ọpọ si gba pe nitori ọrọ ade ọhun ni wọn lọ ṣe ipade le lori.

Idi ti Ladoja se faake kọri lati gba ade idẹ tẹlẹ

Bi ẹ ko ba gbagbe, latigba ti wọn ti gbe ọrọ ade idẹ naa wọnu ilana jijẹ ipo Olubadan ni Sẹnetọ Ladoja to ti figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Oyo ti sọ pe oun ko le ba wọn de ade naa.

Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ lọjọ ti Oba Owolabi Olakulehin gba ade, nibi ti ijọba ti ṣafihan ofin tuntun to de ipo Olubadan, ti ade naa si wa lara rẹ.

Eyi lo mu Oloye Ladoja tun kede lori redio kan niluu Ibadan, pe to ba jẹ dide ade idẹ ọhun lo maa ja oun kulẹ lati jẹ Olubadan, oun ṣetan lati de e.

Ẹwẹ, ẹsẹ ko ni i gbero niluu Ibadan lonii, nibi ti wọn yoo ti maa de ade naa fun Ladoja, nitori pe ọpọ awọn alejo ni yoo wa nibẹ lati ba Otun Olubadan yọ