B‘áwọn ṣọ́ọ̀ṣì bá ń wáàṣù àláàfíà àti ìtẹpámọ́ṣẹ́ dípò ọrọ̀ òjijì, Nàíjíríà yóò dìde padà - Osinbajo

Ibudo ijọsin

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọgbọn Yemi Osinbajo to jẹ igbakeji aarẹ ana lorileede Naijiria, ti fi ẹsun kan awọn ile ijọsin, o ni wọn wa lara iṣoro to n dojukọ Naijiria.

Nibi ayẹyẹ idasilẹ ọdun kejidinlaadọrin ati ipagọ ọdun kejidinlọgọta ti ijọ GOFAMINT, to waye lopin ọsẹ ni Osinbajo ti sọrọ naa lasiko to n ṣe idanilẹkọọ fun awọn ọmọ ijọ ọhun.

Igbakeji aarẹ ana sọ pe kaka ki awọn olori ijọ maa waasu nipa bi awọn ọmọ ijọ, paapaa ọdọ, ṣe le tẹra mọ iṣẹ, iwaasu nipa bi wọn ṣe le di olowo ojiji ni wọn fi n da wọn lẹkọọ.

Osinbajo fi kun ọrọ rẹ pe afi ki awọn ile ijọsin jakejado Naijiria yi iwaasu wọn pada kuro ni didi olowo ati ọlọrọ, ki wọn gbajumọ bi awọn eeyan ṣe le tẹpa mọ iṣẹ.

"Ile ijọsin gbọdọ pada si ibẹrẹ pẹpẹ, nipa iwaasu lori sise iṣẹ akikanju, itara fun iṣẹ ati ṣiṣe iṣẹ isin fun agbegbe ẹni"

O tẹnumọ ọrọ rẹ pe ọna kan ṣoṣo ti Naijiria le gba ni ilọsiwaju ati idagbasoke ni ki awọn ile ijọsin bẹrẹ iwaasu nipa pataki iṣẹ ṣiṣe, dipo ki wọn maa fi ojoojumọ kẹkọọ nipa owo ati ọrọ aye, eyi ti wọn fi n tan awọn eeyan jẹ.

Osinbajo sọ pe awọn ile ijọsin ti kuro ni ilana ti wọn fi bẹrẹ, bii iwaasu nipa igbala ọkan ati titẹpa mọ iṣẹ, to si jẹ pe ọrọ aye ni wọn n le kiri.

“Fun igba pipẹ, ohun kan ti awọn ile ijọsin n ṣe ni kiko ọrọ aye jọ, ti wọn si gbagbe nipa ipe si iṣẹ iwaasu lati ṣagbelarugẹ alaafia, iṣọkan ati idagbasoke awujọ wa.

“To ba jẹ pe lotitọ la nifẹẹ si pe ki Naijiria mu ayanmọ rẹ ṣẹ, ile ijọsin ni lati pada si ibẹrẹ pẹpẹ, nipa iwaasu nipa pataki iṣẹ akikanju, itara fun iṣẹ ati ṣiṣe iṣẹ isin fun agbegbe ẹni.

“Ọna kan ṣoṣo ti a le gba lati mu iwuri ba awọn eeyan wa, ki wọn si jẹ aṣoju gidi nipa ayipada ihuwasi, dipo ki wọn kan maa waasu ihinrere nipa owo lọ.”