Kò sí àṣẹ kankan lórí sísan 70,000 fún àwọn agùnbánirọ̀ - NYSC

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ agunbanirọ lorilẹ-ede Naijiria ti pariwo sita pe iroyin ofege ni iroyin kan to sọ pe ajọ naa ti ṣe afikun si apo owo awọn agunbanirọ lati ma gba owo oṣu to kere ju to jẹ 70,000.
Ajọ naa ni awọn ko ti gba aṣẹ lọwọ awọn ti ọrọ kan pe ki awọn gbe iru igbesẹ bẹ lati ma san owo oṣu tuntun fun awọn agunbanirọ.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Eddy Megwa fi ransẹ si awọn akọroyin lo ti kede ọrọ naa sita, to si ṣapejuwe iroyin ofege gẹgẹ bii eyi to n si awọn eeyan lọna.
NYSC ti wa rọ awọn agunbanirọ pe ki wọn yẹra fun iroyin ofege, ki wọn dẹ ma gba awọn kọlọrọsi ẹda laaye lati si wọn lọna.
Megwa ni “Wọn ti pe akiyesi wa iroyin ofege kan to n si awọn eeyan wa lọna nipa sisan owo oṣu tuntun 70,000 fun awọn agunbanirọ.
“Iro nla ni iroyin, to si jina si otitọ.
“A n rọ awọn obi, alagbatọ, agunbanirọ ati gbogbo araalu pe ki wọn yẹra fun iroyin naa nitori awọn ko ti gba aṣẹ lọwọ ijọba apapọ lori ọrọ owo oṣu tuntun fun awọn agunbanirọ.
“A wọn agunbanirọ mọ ibi ti iroyin to ba tọwọ wa jade ma n wa.”
Bakan naa lo tun kesi awọn iroyin pe ki wọn jawọ ninu gbigbe iroyin ti wọn ko fi di rẹ mulẹ jade sita fun araalu.
“A n kilọ fun awọn akọroyin ayelujara pe ki wọn jawọ ninu gbigbe iroyin ofege sita paapa eyi ti jẹ mọ ajọ NYSC.”

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/officialnyscng/















