Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó ń ṣe àyájọ́ 8/8 yìnbọn pa ọ̀gá àgbà ilé ìtura kan ní Ilorin

Aworan awọn ẹlẹgbẹ okunkun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbebọn kan ti wọn furasi pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ni a gbọ pe wọn ya bo ile itura kan "Febby Kay Suite" to kalẹ si agbegbe Olunlade ni ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara, wọn si gbẹmi ọga agba ile itura naa.

Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, osu kẹjọ ọdun 2024 ni iṣẹlẹ buburu yi sẹlẹ, nigbati awọn eniyan meji ti wọn mura bi alabara, tan arakunrin naa jade lati inu ọfisi rẹ, ki wọn to pa a.

Iwadii fihan pe orukọ oloogbe naa ni Anthony Kayode Balogun, ọjọ ori rẹ si to mẹtalelogoji.

Ni ibi ifimu finlẹ wa ni awọn kan sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn n soro ayajọ 8/8 gẹgẹ bi wọn ṣe ma n se 7/7.

Wọn ni o seese ki oloogbe naa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun nitori wọn ti kọkọ sa a lada ti ko wọle ki wọn to yinbọn fun un, ti awọn oun ija yoku naa si wọle sii lara.

Ikun ni wọn ti yinbọn fun aburo mi lẹyin ti wọn tan an jade sita - Ẹgọn oloogbe naa

BBC News Yoruba ṣabẹwo si ile awọn oloogbe naa ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan-an, gbogbo ẹbi si ni wọn wa ninu ọfọ ati ibanujẹ.

Arabirin Ojo Grace ti o jẹ ẹgbọn oloogbe to bawa sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe Anthony nikan ni ọkunrin ninu gbogbo ọmọ ti iya awọn bi, ohun si lo jẹ alabojuto otẹẹli mama awọn.

Arabirin naa sọ bi iṣẹlẹ laabi naa se waye. "ile ni mo wa ni alẹ ọjọ kẹjọ sugbọn ni nkan bi ago mẹsan abọ, iyawo aburo mi pe mi ni ipe pajawiri pe ki n ma bọ ni ileewosan ẹkọsẹ ti ipinlẹ Kwara.

Arabinrin Ojo sọ pe wọn sa lada ni gbogbo ara, wọn si yinbọn fun un ni ikun.

"Igba ti mo bi awọn ọrẹ rẹ ni bi o se sẹlẹ nitori wọn ma n wa lọdọ rẹ ni gbogbo igba, ọkan ni ohun ti jade lọ ra ounjẹ nigbati awọn agbebọn naa de, ekeji ni ohun o si ni ibẹ rara sugbọn iro ibọn ti ohun gbọ lo mu ohun sare sibẹ.

Se loootọ ni oloogbe jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun?

Lori ohun ti awọn nkan n sọ pe Anthony jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun nigba aye rẹ, arabinrin Grace sọ pe aburo ohun jẹ onirẹlẹ eniyan to gbaju mọ isẹ rẹ.

O fi kun-un pe, lotitọ, gbogbo nkan kọ ni Anthony ma n sọ fun ohun nitori ohun jẹ obinrin, fun idi eyi, ohun kole sọ boya o jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun abi kiise.

Nigba ti BBC News Yoruba de otẹẹli ti wọn ti sọsẹ naa ni alẹ ọjọ kẹsan an, ko si osisẹ tabi onibara kan nibẹ, gbogbo ilẹkun ni o wa ni titi pa bakan naa ni agbegbe ibẹ pa lọlọ laisi ẹyẹ.

Awọn ọlọpaa ni àwọn ti nawọ gan afurasi kan

Kọmisana ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni nise ni ajọ ọlọpaa n se isẹ takun takun lọwọ lati ri pe ifẹhonuhan ebi to n lọ lọwọ ko mu rogbodiyan dani, awọn sise aseyọri.

O ni sugbọn 8/8 yi jẹ ohun tuntun, o salaye pe 7/7 ti wọn se ni osu to kọja, gbogbo ona ti awọn ẹgbẹ okunkun fẹ gba sọsẹ lawọn ti gbaradi fun, ko si si wahala tabi itajẹsilẹ kan ni ipinlẹ Kwara.

O ni lotitọ lo seese fun ọlọpaa lati ma le dawọ gbogbo iwa ọdaran duro, sugbọn ko seese fun ọdaran kan lati lọ lai jiya isẹ ọwọ rẹ.