Ọ̀dọ́kùnrin kan rèé tó pàdánù ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì lójú ogun àmọ́ tí kò jẹ́ kí ìpèníjà rẹ̀ dí i lọ́wọ́ láti jẹ́ èèyàn láyé
Ọdọkunrin kan Oleksandr Budko ree to jẹ akọni ologun lorilẹede Ukraine ati ajafẹtọọ awọn akanda ẹda ti o si tun gbami ẹyẹ ninu Invictus Games ti Ọmọba Harry gbe kalẹ ti i se idije agbaye fawọn ologun to farapa loju ija.
Budko ni gbogbo erongba oun lati rìnrìn ajo ṣe iwadii nigba agbaye, amọ, nigba ti ogun bẹrẹ, oun ni lati kopa ninu rẹ.
Eyi lo jẹ ki Budko gbe erongba rẹ si ẹgbẹ kan.
Budko jẹ ọkan lara awọn ọpọlọpọ ọkunrin ọmọ orílẹ̀-èdè Ukraine to darapọ mọ ileeṣẹ ologun lati kọju ija si Russia.
Ni oṣu Kẹjọ ọdun 2022 ni Budko padanu ẹsẹ rẹ mejeeji nigba ti ado oloro kan bu gbamu ni apa ariwa Ukraine.
Budko ni "o dabi ẹni pe ilẹ n bo mi mọlẹ.
Ṣa deedee ni mo bẹrẹ si ni jẹ irora lẹsẹ mi.
Eyi lo fa a ti wọn fi ge ẹsẹ mi mejeeji ti mo si bẹrẹ si ni lo ẹsẹ atọwọda onirin."
Amọ, Oleksandr ko jẹ ki ohun to sẹlẹ si i di i lọwọ lati da ohun to fẹ jẹ laye.
Lẹyin iṣẹlẹ yii ni o bẹrẹ si maa sọrọ lori itakun ayelujara lati maa pe akiyesi awọn eeyan si irora ti o la kọja nigba ti wọn ge ẹsẹ rẹ mejeeji.
Bayii ni Oleksandr ṣe di sọrọsọrọ lori ayelukara.
Oleksandr salaye pe ninu kẹkẹ awọn alailera loun maa n joko si ki oun to bẹrẹ si maa lo ẹsẹ irin niluu Kyiv, eyi to jẹ ki oun mọ iṣoro t'awọn iru eeyan bi toun maa n la kọja.
Oleksandr ni o ṣoro lati sọda loju titi fun iru eeyan bi toun lai lo kẹkẹ.
Eyi maa n jẹ ko dabi ẹni pe onitọun ko ri ile aye wa.
Ni bayii, Oleksandr yoo kopa ninu fiimu agbelewo kan, ti wọn n pe ni The Bachelor eyi to da lori ere Amerika kan.
Fiimi agbelewo yii ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan maa n wo to si maa n ṣafihan ihuwasi wọn s'awọn akanda eeyan.
Oleksandr ni aye oun ti dara bayii ju ti igba ti ogun ko tii ṣẹlẹ gan an lọ ki oun to f'ẹsẹ ṣeeṣe.
Olotu ileeṣẹ tẹlifisan to n gbe ere agbelewo naa sori afẹfẹ, Natalia Franchuk ni oun maa n saba beere pe ta ni yoo jẹ akọni ninu ere The Bachelor.
O ni oun tun maa n beere pe ta ni o wa lati ibi wọn ti n jagun.
"Nitori o ye wa ipo tawọn mọlẹbi awọn ologun wa lọwọ yii."
Amọ bi o ṣe ri pe Oleksandr jẹ akọni to ti ja loju ogun lo jẹ ki beere ibeere yii.
Oleksandr ni oun yoo kopa ninu ere agbelewo naa lati ṣe iranwọ fáwọn akẹgbẹ oun ki oun si tun le jẹ ohun iwuri fun wọn.
Igbagbọ Oleksandr ni pe awọn eeyan ti ko ni ẹsẹ le gbe igbe aye to dara.
















