"Ìjàmbá ọkọ̀ ló kán egungun ẹ̀yìn mi kí wọ́n tó gbé irin si, síbẹ̀ mo wa alùpùpù láti Kenya wá sí Naijiria"

Àkọlé fídíò, "Ìjàmbá ọkọ̀ ló kán eegun ẹ̀yìn mi kí wọ́n tó gbé irin si, síbẹ̀ mo wa alùpùpù láti Kenya wá sí Naijiria"
"Ìjàmbá ọkọ̀ ló kán egungun ẹ̀yìn mi kí wọ́n tó gbé irin si, síbẹ̀ mo wa alùpùpù láti Kenya wá sí Naijiria"

Obinrin to gun alupupu lati orilẹede Kenya wa si Naijiria, Ebiade Joy Udo ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe irin lo wa ni ọpa ẹyin oun, ipenija naa ko di oun lọwọ lati ṣe ohun to wu oun.

Ẹbiade lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Ọdọbinrin ọhun sọ pe ipenija naa gangan lo ru oun soke lati gun alupupu la ọpọ orilẹede kọja.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, nnkan bii oṣu mẹrin ati orilẹede mẹsan an ni irinajo naa gba a ko to de Naijiria lati Kenya.

Ijamba ọkọ lo kan eegun ẹyuin mi

Ebiade Joy

Ebiade ṣalaye fun BBC pe lasiko ti oun wa ni ẹni ọdun mẹtalelogun ni oun ni ijamba ọkọ kan, eyii to gba ọpa ẹyin lọwọ oun.

O ni “mo lọ fun idije arinrinoge kan ni ipinlẹ Edo, ni Naijiria, nigba ti mo dẹ n pada lọ sile, ọkọ ti mo wọ takiti ni Ọrẹ, laimoye igba.

“Oriṣiriṣi nnkan lo ṣẹlẹ, ẹni to wa lẹyin mi ko si laye mọ, ẹyin mi ni mo fi balẹ.... lẹyinorẹyin, wọn tọju mi, ẹyin mi wa daadaa nisinyin.

“Awọn ohun ti wọn fi de irin si mi lẹyin maa wa nibẹ titi ti mo maa fi ku, ṣugbọn wọn wa lẹyin mi, wọn n jẹ ki n rin.”

Ebiade sọ pe lẹyin ijamba naa loun pinnu pe ko ni di oun lọwọ lati gbe igbeaye to wu oun.

Ki lo ṣẹlẹ lasiko ninu irinajo lati Kenya si Naijiria?

Nipa iriri rẹ lati Kenya si Naijiria Ebiade sọ pe oriṣirṣi nnkan lo ṣẹlẹ.

O ni “mo wa ọkada mi gba aarin orilẹede mẹsan an, mo pade oniruru ẹranko igbẹ bii ejo ‘black manba’ to fo lemi lori.

“Mo ni iṣoro pẹlu awọn ẹṣọ alaabo nitori ilẹ Afrika ree, gbogbo wa mọ pe eto abo le lawọn ibi kan, ẹ dẹ mọ pe emi nikan ni mo n lọ gẹgẹ bii obinrin.

O fi kun pe oun ni ọpọ idojukọ nipa iwe irinna gbigba, epo to n rọ sinu alupupu naa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ebiade ṣalaye siwaju si nipa ohun toju rẹ ri ni Angola, nibi to ti ṣubu lule ti awọn eeyan si kọ lati ṣe iranlọwọ fun oun bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo wa nibẹ.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti akinkanju ọdọbinrin naa ba BBC Yoroba sọ.