Ohun tí a mọ̀ rèé nípa àwòrán ìgbéyàwó Babalawo Alebiosu tó lu orí ayélujára pa

Babalawo Alebiosu ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, alebiosu_adewale/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja osere tíátà tó fi ilu Abeokuta,ipínlẹ̀ Ògún ṣebugbe, Ọgbeni Adewale Alebiosu tí gbogbo eeyan mọ sì Awo l’Ọyọọ, tí fidi ẹ múlẹ̀ pé lotitọ ni oun ṣegbeyawo tí iroyin ati fọto rẹ gba orí ẹ̀rọ ayelujara kan.

Alebiosu fidi ọrọ yii múlẹ̀ nígbà tó ń ba akọroyin BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lórí aago.

Oṣere tiata to maa n kopa babalawo naa sọ pe o tí le lọdun mọkanla toun ati iyawo naa ti fẹra, ṣugbon ti awon ko ṣegbeyawo, bo tilẹ jẹ pe awọn ti bimọ.

‘’ Fọto igbeyawo mi ti ẹ ri lori ayelujara ki i ṣe irọ rara, emi ati iyawo mi lọ si Registry Ikoyi, niluu Eko, wọn si so wa pọ ni.

‘’Iyawo mi ti n ro o tẹlẹ pe mo kan fẹẹ yan oun jẹ ni, pe boya mi o ni i gbe e niyawo mọ lẹyin to ti bimọ. ‘’Ṣugbọn mọ fẹẹ fi da a loju pe ki i ṣe ẹtan la ṣe lọọ ṣegbeyawo alarede naa’’

Bẹẹ ni Alebiosu wi.

O fi kun un pe aisi owo ati bi nnkan ṣe ri latigba naa lo fa a toun ko ṣe ni anfaani lati ṣegbeyawo fun igba pipẹ.

Ki ọdun yii too pari, Babalawo Alebiousu sọ pe oun yoo ṣi ṣegbeyawo alarinrin fun iyawo yii, toun yoo pe gbogbo eniyan waa ba oun yọ.

Ta a ni Babalawo Alebiosu?

Babalawo Alebiosu

Oríṣun àwòrán, Others

Laarin ọdún 2022 sì ọdun 2023 ni iroyin osere tó maa ń ṣawada pọfọ, Adewale Alebiosu, gba orí ayelujara kan nígbà tó beere iranlowo lọ́wọ́ àwọn awọn ọmọ Naijiria.

Gbajugbaja pasitọ nni, Agbala Gabriel torukọ rẹ gan-an n jẹ Ademola Amusan, dide iranlọwọ fun oṣere yii nigba naa.

Iranlọwọ owo ni Agbala Gabriel ṣe fun Babalawo Alebiosu, ni nnkan bii oṣu diẹ sẹyin ni oṣere naa si bẹrẹ okoowo ẹja, adiẹ ati tọki tutu l’Abeokuta.

Alebiosu ṣafihan bí igbesi aye rẹ ṣe kú díẹ̀ kaato nigba naa, o ṣalaye pe iwa aibitikita ti àwọn oṣere to gunke agba hu si òun, ni ipa lori igbésí ayé oun.

Oṣere to ṣẹṣẹ gbeyawo yii wa lara awọn to bù ẹnu àte lu àwọn adari ẹgbẹ́ TAMPAM, o ni wọn ko kọbi ara sì igbe ayé irọrun àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba ni Awo l’Ọyọọ ti sọ pe

kò sí ìfẹ́ láàárín àwọn tí wọ́n ń ṣe sinima agbelewo Yoruba.

O ni lójú iwoye toun, àwọn tí wọn ń ṣe sinima Yoruba kí i fẹ́ rán ara wọn lọ́wọ́.