Ọlọ́pàá rí òkú ọkùnrin tó ń múra bíi obìnrin lójú títì l’Abuja, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Aworan Josephine Adeh

Oríṣun àwòrán, Josephine Adeh/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa olu ilu orilẹede Naijria, Abuja ti bẹrẹ iwadii lori iku ọkunrin kan to maa n mura obinrin, eyi ti wọn ba oku rẹ ni titi.

Alukoro ọlọpaa fun ilu Abuja, Josephine Adeh, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita l’Ọjọbọ,ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ ọdun 2024.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’a gba ipe pe wọn ju oku kan si oju ona marose Katampe-Mabushi, a ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ sibẹ, wọn si ri i pe ọkunrin ni ẹni to ku naa, ṣugbọn o mura bi obinrin, ko si si ami idanimọ kankan lara rẹ’’

Ileewosan to wa lagbegbe Maitama, niluu Abuja ni wọn gbe oku naa lọ bi Alukoro ṣe wi.

Ọsibitu naa ni wọn dokita si ti fidi ẹ mulẹ pe ẹni ti wọn gbe wa naa ti ku.

Lati mọ iru iku to pa ọkunrin to n ṣe bii obinrin naa, Kọmiṣanna ọlọpaa ilu Abuja, Benneth Igweh, yara paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ kia.

Wọn fi kun un pe awọn ko ni i fi abajade iwadii naa falẹ tawọn yoo fi kede rẹ fun gbogbo eniyan.

Apo ifalọwọ kan ati awọn nnkan eelo pẹẹ-pẹẹ-pẹẹ ni wọn ba lẹgbẹẹ oku naa, gẹgẹ bi aworan tawọn ọlọpaa fi kede iṣẹlẹ naa ṣe ṣafihan rẹ.