Aráàlú nípa láti kó lóri àti fòpin sí àyájọ́ táwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn máa ń ṣe lọ́dọọdún - Ọlọ́pàá

Pẹlu bi ileeṣẹ ọlọpaa se n pariwo nipa ayajọọ ẹgbẹ okunkun ati awọn iṣẹ ibi ti wọn n fi aṣiko naa se, ki lo de ti ayajọ ọjọ ẹgbẹ okunkun to maa n waye lọjọ keje oṣu keje ati ọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ lọdọọdun ko ti fi di ohun igbagbe?
Ileeṣẹ BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lati ṣalaye akitiyan ileeṣẹ ọlọpaa lori ati fopin si awọn ẹlẹgbẹ okunkun.
Hundeyin ni bo ti lẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa n sa gbogbo agbara lati ri pe opin de ba awọn ẹgbẹ okunkun sugbọn o ṣe koko ki awọn araalu fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa.
"Bi mo se n bayin sọrọ yii, ọpọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun ni o wa ni ahamọ, ti wọn yoo si foju ba ile ẹjọ laipẹ.
"Ileeṣẹ ọlọpaa n sa agbara rẹ lati koju iṣorọ naa sugbọn o ṣe koko ki awọn araalu naa se ti wọn.
"Ọpọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun yii lo ti wa ni ọgba ẹwọn bayii."
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opelola ni tiẹ sọ pe o se koko ki awọn ma pe akiyesi araalu si awọn iṣẹlẹ bo ti lẹ jẹ pe o soro pe ki ariwo jade sita pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun wa ni ayika.
"Bi a ṣe n pe akiyesi awọn eeyan si awọn ayajọọ yii ni a n pe ni o n bọ o n bọ, awọn ni a n dẹ de.
"A ko fiya gba ki irufẹ ayajọọ naa waye nibikibi, ti a ri n ri pe n da awọn araalu lẹkọ nipa ohun ti wọn ni lati se.
"A wa nibi lati ri pe ohun to lodi sofin ko waye mọ."
Kò sí ààyè fún àyájọọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn kankan l’Osun lónìí ọjọ́ kẹ́jọ oṣù Kẹ́jọ ''8/8'' - Ọlọpaa
Pẹlu bi olobo ṣe ta ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti pinnu lati ṣe ayajọ ẹgbẹ wọn lonii, Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti kilọ pe apẹjọ bẹẹ ko gbọdọ waye nibi kankan l’Osun.
Ninu atẹjade kan ti SP Opalola, alukoro olopaa Osun fi sita lo ti kilọ naa l’Ọjọru, ọjọ keje, oṣu kẹjọ 2024.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’iwadii kikun ti fi ye wa pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n gbaradi lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ẹgbẹ wọn lọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ (8-8-2024).
‘’Latari eyi ni ileeṣẹ ọlọpaa Osun ṣe n kilọ fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati awọn eeyan mi-in ti iwa ọwọ wọn ko mọ, lati ma ṣe dan an wo rara.
‘’Gbogbo igbese wọn pata ni awa ọlọpaa n tọpinpin rẹ, yoo dara ki wọn tete gbagbe igbesẹ to le fa rogbodiyan.
‘’A ko ni i faaye gba ipẹjọ yoowu to le mu itajẹsilẹ wa, tabi ti yoo da omi alaafia ipinlẹ Osun ru.’’
Atẹjade naa fi kun un pe ki i ṣe ọlọpaa nikan ni yoo koju awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun, wọn ni apapọ ọmọ ogun JTF yoo kun wọn lọwọ pẹlu.
Eyi ni wọn fi pe awọn obi ati alagbatọ, pe ki kaluku kilọ fun ọmọ rẹ.
Wọn ni ida ofin yoo ba ẹni yoowu tọwọ ba tẹ lori ẹsun yii .
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa Osun rọ awọn olugbe ipinlẹ naa lati fi oju ṣori, ki wọn si tete fi ohun ifura ti wọn ba ri to ọlọpaa leti.
Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa maa n ya ọjọ keje, oṣu keje gbogbo ọdun sọtọ lati ṣe ayẹyẹ ọdun wọn.














