Èmi ni mo pe ọmọ mi kó jáde wá fẹ̀hónúhàn tí ó fi ṣàgbákò ikú òjijì - Ìyá ọmọkùnrin tó kú

Oríṣun àwòrán, Maryam Musa
- Author, Buhari Muhammad Fagge
- Role, Multimedia Journalist
- Reporting from, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ifẹhonuhan to lodi si inira ati ebi ni Naijiria to bẹrẹ ni Ọjọ kinni, Oṣu Kẹjọ ti gba ẹmi awọn eeyan kan, ti ọkan ninu wọn si jẹ Usman Ismail Muhammad, ẹni ọdun mọkanlelogun.
Iya re lo tẹnumo fun un pe ko darapo mo oun fun iwode to waye ni ipinle Kano, ni iwo oorun ariwa Naijiria. Sugbon asita ibọn ṣekupa lojo naa.
Idile yii ni wọn ti jẹ ogun ni ye n tiraka lati gbe igbe aye to rọrun, gẹgẹ bi ọmọkunrin akọkọ, ọpọlọpọ ojuse wa lọrun Usman. Eyi to pẹlu awọn iyawo mẹta ti baba rẹ, ẹni ti o jẹ alaga kansu ijọba ibilẹ fẹ sile.
Bi o tile je wi pe Usman ni ero lati darapo mo awon olufẹhonuhan, nigba ti iya re n kuro nile laaro ojo Isẹgun, ko tii setan. Ṣugbọn o tẹsiwaju lati pe e lori foonu, nitori atako ni ọna kan ṣoṣo lati ṣe afihan ohun to n ba wọn ninu jẹ ni lati kopa ninu iwọde naa.
“Mo pe ọmọ mi wa si ibi iwọde, ohun ti n ko mọ ni pe mo n pe e lati wa pada iku rẹ,” Maryam, iya oloogbe, sọ fun BBC. O ni oun n pe lati rii daju pe o fi ile silẹ lati wa darapo mọ oun nibi iwọde #EndBadGovernance.
Ki lo sẹlẹ nigba ti wọn de ile ijọba
Saaju ọjọ naa, “O mu ọkan ninu bata rẹ jade, sokoto sokoto buluu kan ati ẹwu funfun kan,” ni igbaradi fun iwọde naa, o sọ. Lojo ti won n fehonu han, won darapo mo egbe awon ti won yabo lo si ile ijoba ipinle Kano.
Nibẹ ni wọn ti nireti lati sọ ẹdun ọkan wọn fun gomina ipinlẹ naa, tabi ẹnikẹni ti yoo jade lati gbọ ọrọ wọn. Gege bi ọrọ rẹ, ko pẹ ti wọn si ile gomina, ti wọn duro sita ile ijoba pelu awon yooku ni awọn ọlọpaa bẹrẹ sini ma yin tajutaju.
Igba ikẹyin ree to ri Usman.
"Efin ti wa ninu gaasi tajutaju ti gba gbogbo oju ọjọ, Ẹru ba mi nitori naa a sa lọ," Maryam sọ pe oun ni lati gun ọkada se ile. Ṣaaju ki iroyin to sọ fun un pe ọmọ rẹ ti jade laye ni ara ti sọ pe ọmọ rẹ ti ku ninu rogbodiyan to bẹ silẹ.
“Lati igba ti ibon yiyan naa ti ṣẹlẹ, irora wa ninu ọkan mi. Ati pe mo kan mọ pe nnkan to buru ti ṣẹlẹ, ”o sọ.
Ninu ọrọ ikẹyin pẹlu Usman ṣaaju iṣẹlẹ naa, o sọ fun u nipa bi igbesi aye se le fun ẹbi ati bii o se lọ fun ọjọ mẹrin lai ṣe ounjẹ.
“O fi mi da mi loju pe awọn idojukọ yii yoo di ohun atijọ laipẹ ni kete ti o ba di oṣiṣẹ ilera,” ni Maryam ranti. Sugbon Usman ko le mu awon ileri re se fun un mọ.
Usman ti kọ ẹkọ fun iwe-ẹri nọọsi ni ile-ẹkọ awọn nọọsi, ṣugbọn ko ti ri iṣẹ ni ẹka eto ilera, iya rẹ rii pe o ṣiṣẹ pẹlu ẹgbọn rẹ to n ta awọn aṣọ ni ọja.
Ni ọdun meji ṣiṣẹ pẹlu aburo iya rẹ, Usman ti n gba owo osu to jẹ N45,000 ($ 30), ti idaji owo yii si n lọ fun ipese ounje fun ẹbi. Gẹgẹbi Maryam, o tun ṣe atilẹyin fun awọn aburo rẹ nipa sisanwo owo ile-ẹkọ.
Ni ọjọ Wẹsidee - ọjọ kan si iwọde naa – nigba ti o san owo-oṣu rẹ, o yanju diẹ ninu gbese ti ẹbi naa jẹ lati rira nnkan ounjẹ. Iyoku owo oṣu naa wa ni apo rẹ nigba ti ibọn ba. Sugbon nigba ti won gbe oku re wa, gbogbo owo lo ti lo, iya re ni.
Nígba ti wọn yẹ ara rẹ wo, ọna meji ni ibọn ti ba: ẹyìn rẹ ati ejìka rẹ.
“Iku rẹ yoo jẹ aleebu lailai ninu ọkan mi,” ni Maryam sọ, “A fẹ idajọ ododo lati ọdọ ijọba”.
Ki ijọba apapọ ati ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Ni ọjọ Aiku, Aarẹ orilẹede Naijiria Bola Tinubu, ninu ọrọ ori tẹlifíṣọn, ni otitọ ni pe ipadanu ẹmi waye ni oriṣiriṣi ni orilẹ-ede lẹyin awọn iwọde naa. Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpa ṣiyemeji lati jẹwọ ipadanu awọn ẹmi, paapaa eyi ti ọtan ibọn wọn sekupa.
Nigba ti BBC kan si Abdullahi Haruna Kiyawa, agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Kano, lati sọrọ nipa iku Usman, o sọ pe isẹ naa ni wọn se pẹlu awọn ileeṣẹ aabo miiran. Eyi to ni o jẹ ki o ṣoro fun u lati tọka si ẹni ti o yinbọn pa ọdọmọkunrin naa.















