Mọ̀ sí i nípa 'Ask Lagos,' ètò tuntun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé kalẹ̀ fún aráàlú láti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn

Oríṣun àwòrán, Governor Sanwo-Olu @X
Iṣakoso Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti gbe ṣe agbekalẹ eto kan fun awọn eeyan ipinlẹ yii, eyi ti wọn pe ni Ask Lagos.
Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso, lo ṣi aṣọ loju agbekalẹ naa loju opo X rẹ.
Loju opo naa ni Omotoso ti ṣalaye, pe Ask Lagos yoo gbera sọ loju opo X lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii.
Aago mẹfa irọlẹ lo ni eto naa yoo bẹrẹ, nibi toun yoo ti maa da awọn eeyan lohun nipa Ask Lagos, ti araalu yoo ti le beere ohun to ru wọn loju, ti ifọrọwerọ yoo si maa lọ ni pẹrẹwu.
Ki ni Ask Lagos?

Oríṣun àwòrán, Gbenga Omotoso@ X
Nigba to n ṣalaye ohun ti Ask Lagos jẹ gan-an, Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Eko, sọ pe, ‘’ọna kan lati di alaafo ti ko jẹ ki ikansira ẹni rọrun laarin ijọba ati awọn olugbe Eko ni eto yii jẹ.
'Nnkan to jẹ ka gbe e kalẹ ni pe ọpọ eeyan ti a n pade ati awọn ti wọn maa n kọwe si wa maa n sọ pe awọn nnkan kan wa tijọba n ṣe ti awọn ko mọ, ti ko ye awọn.
''Wọn maa n sọ pe awọn nnkan mi-in wa tawọn fẹ latọdọ ijọba ṣugbọn tawọn o mọ ẹni tawọn maa ba sọrọ.
''Awọn nnkan bii ọrọ ilẹ, abi mo fẹẹ kọle mi o, ki n too bẹrẹ si i kọ ile naa, ki ni mo maa ṣe.
Iyẹn la fi waa wo o, pe gbogbo ibeere tẹ ẹ ba ni lati beere gẹgẹ bii araalu, ẹ beere lọwọ ijọba.
''A gbe e kalẹ nilana tẹ ẹ fi le ri kọmiṣanna ba sọrọ, tabi alẹnulọrọ mi-in ninu ijọba.
Fun awọn eeyan ti wọn ko ba ni anfaani si oju opo ayelujara, Kọmiṣanna eto iroyin l'Ekoo naa sọ pe ọna mi-in wa ti wọn tun le gba kan sijọba.
'' Ijẹta ode yii ni Gomina paṣẹ pe ka fi awọn nọmba ibaraẹnisọrọ mẹta kan sita, pe ki awọn araalu maa pe e, a si ṣe bẹẹ.
'Lẹnu alẹ ijẹta yẹn ti a ṣi tẹlifoonu naa titi di ana, ọgọọrọ eeyan lo ti pe, to jẹ pe o ya wa lẹnu gan-an.
''Ṣugbọn ko si igba ti wọn pe ti wọn o ri eeyan nibẹ lati sọ nnkan to ba yẹ ki wọn ṣe fun wọn, tabi dahun ibeere wọn.''
Nipa anfaani ti 'Ask Lagos' yoo jẹ fun awọn olugbe Eko ati ijọba ipinlẹ yii, Omotoso sọ pe yoo jẹ ki araalu mọ pe wọn ko sọrọ si afẹfẹ lasan, yoo fun wọn ni anfaani lati mọ pe ijọba wa nikalẹ lati gbọ ohun ẹbẹ wọn.
O ni gbogbo ohun ti wọn ba fẹẹ mọ ko ni i ṣoro fun wọn lati mọ ki wọn too dawọle e. Eyi to ba si ru wọn loju yoo di ohun ti ijọba tan imọlẹ si.
Fun ijọba funra rẹ, Kọmiṣanna sọ pe 'Ask Lagos' yoo jẹ ki ijọba mọ ibi ti bata ti n ta araalu lẹsẹ, yoo si jẹ kijọba mọ ohun ti wọn n fẹ, ati ohun to n mu inu wọn dun sijọba.

Oríṣun àwòrán, @gbenga_omo X














