Ta ni Tim Walz tí olùdíje Democrat, Kamala Harris kéde gẹ́gẹ́ bí olùdíje fún ìpò igbákejì ààrẹ l'Ámẹ́ríkà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oludije fun ipo aarẹ orilẹede Amẹrika labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Democratic Party, Kamala Harris ti yan Tim Walz gẹgẹ bi igbakeji rẹ.
Kamala Harris kede Tim Walz loju opo X rẹ gẹgẹ bii oludije fun ipo igbakeji aarẹ labẹ rẹ .
“Mo layọ lati kede pe mo ti ni ki Tim Walz jẹ igbakeji mi.
Gẹgẹ bii gomina, olukọni ere idaraya, olukọ ile ẹkọ ati ajagunfẹyinti.
O ti ṣe ohun meremere fun awọn idile lọpọlọpọ bii tirẹ. Inu mi dun lati ni i lara ikọ mi.”

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ki ni idi ti Kamala Harris fi yan Walz?
Iwọnba eeyan perete lo ro ọrọ kan Tim Walz to jẹ gomina ipinlẹ Minnesota lati dije gẹgẹ bi igbakeji aarẹ fun Kamala Harris.
Olukọ ile ẹkọ giga tẹlẹ naa di aayo ọpọ lẹgbẹ oṣelu Democratic nitori iwoye wọn pe o jẹ ẹni to le ju ogulutu si oludije ẹgbẹ Republican, Donald Trump daadaa.
Bi o tilẹ jẹ wi pe lọsẹ diẹ sẹyin iwọnba diẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic to mọ okolo Walz lọyọ oṣelu amọṣa lawọn igba miran ẹfọn a maa ja baluu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ta ni Tim Walz?
- Ki wọn to yan an gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Minnesota lọdun 2018, ọpọ lo mọ ọ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic to to gbangba n sun lọyẹ ti muṣemuṣe rẹ si gba muṣe.
- Ọdun mejila ni Walz lo gẹgẹ bi aṣofin apapọ lorilẹede Amẹrica.
- Apejẹ to fun Donald Trump to n dije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Republican ati igbakeji to yan JD Vance gẹgẹ bi “arameeri” kun ara orukọ ti ọpọ ko jẹ gbagbe lara Trump.
- Ẹni ọgọta ọdun ni Tim Walz, oun si lo lewaju iwọde to waye ni ipinlẹ Minnesota lọdun 2020 lori iku George Floyd ni Minneapolis.
- Funrarẹ lo ko awọn ikọ ọmọ ogun apapọ jade lati pa ina wahala to bẹ silẹ lasiko iwọde naa.
- O le ni ogun ọdun to lo gẹgẹ bi ara ikọ ọmọogun kogberegbe apapọ ni Amẹrika, eyi ti wọn n pe ni “National Guard”
Iyi nla ayeraye ni yiyan ti wọn yan mi gẹgẹ bi igbakeji oludije fun ipo aarẹ -Tim Walz

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tim Walz pẹlu ti sọrọ lori yiyan ti oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Democratic, Kamala Harris yan an gẹgẹ bi igbakeji rẹ.
Ninu ọrọ to kọ soju opo X ti ọpọ mọ si Twitter tẹlẹ, Tim Walz sọ pe, “Iyi ayeraye ni fun mi lati darapọ mọ @kamalaharris ninu eto ipolongo ibo yii.”
O ni Harris n “fi han gbogbo wa iru awọn oṣelu ohun to ṣeeṣe”.
“O ran mi leti ọjọ akọkọ akẹkọọ ni ile ẹkọ, Nitori naa ẹ jẹ ka mu iṣẹ yi ṣe ẹyin eeyan mi.”

Oríṣun àwòrán, screenshot
Awọn eekan ẹgbẹ Democratic ti n kan saara si yiyan ti wọn yan Walz
Olori tẹlẹ fun ile Aṣojuṣofin lorilẹede Amẹrika, Nancy Pelosi ti kan saara si Walz ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lori eto kan lorilẹ ileeṣẹ mohunmaworan MSNBC
“Eeyan to dara ni Tim Walz.”
Pelosi ni oun mọ Walz daradara lẹyin ti wọn jọ lo saa ni ile igbimọ aṣojuṣofin.
“Ọkan pataki lara ogunna-gbongbo ẹgbẹ oṣelu Democratic ni”















