Wo bí àwọn èèyàn Bangladesh ti ṣe ìwọ́dé tí Olóòtù ìjọba orílẹ́èdè náà sì kọ̀wé fipò sílẹ̀ sálọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Bangladesh ni ohun to sẹlẹ ya lẹnu, ti wọn si n reti ohun ti yoo waye lẹyin ọjọ kan ti Olootu ijọba orilẹede naa, Sheikh Hasina sa dede kọwe fipo silẹ, to si saa kuro lorilẹede naa.
Ọgagun orilẹede na ni ijọba fidi hẹ yoo gba akoso orilẹede naa, ti wọn yoo si kede asiko ti eto idibo tuntun yoo waye.
Ọpọ eeyan lo yabo ile Hasina ni Dhaka lọjọ Aje, ti wọn si bẹrẹ si ni ma fọ ile naa, ti rogbodiyan naa si ṣekupa eeyan to le ni ọgọrun.
Hasina, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin lo kọwe fipo silẹ lẹyin ti ifẹhonuhan lọjọ gbọrọ bẹ silẹ lorilẹede naa.
Ọpọ iroyin ti a ko le fidi rẹ mulẹ ni o ṣalaye pe Hasina ti balẹ si orilẹede India lọjọ Aje, ti igbagbọ si wa pe yoo morile ilu London.
Kete ti Hasina kọwe fipo silẹ ni Aarẹ orilẹede naa, Mohammed Shahabuddin palaṣẹ pe ki wọn tu olootu ijọba tẹlẹ to wa ni atimọle, Khaleda Zia ati gbogbo awọn akẹkọọ ti ijọba ti mọle lasiko ifẹhonuhan to tako ijọba.
Bawo ni ifẹhonuhan naa se bẹrẹ ?
Ni ibẹrẹ oṣu keje ni ifẹhonuhan yii bẹrẹ, ti awọn akẹkọọ fasiti si tu sita lati tako ilana ijọba lori ọrọ iṣẹ.
Awọn akẹkọọ ati awọn to lewaju fun ifẹhonuhan naa ni igbesẹ ijọba ni ko ba ojumu, ti ijọba si ni lati wọgile igbesẹ naa.
Botilẹ jẹ pe ijọba se pupọ ninu ohun ti wọn, iwọde naa ni yipada, ti ọpọ si bẹrẹ si ni tako ilana ijọba
“Ki se awọn akẹkọọ nikan mọ, ọpọ awọn araalu lo ti darapọ mọ ifẹhonuhan naa,” Dokita Sa,mina Luthfa sọ fun BBC.
O le ni eeyan 300 to padanu ẹmi wọn lasiko ifẹhonuhan naa.
Olootu ijọba kede ofin konilegbe ni awọn agbegbe kan, ti wọn si ja lilo ẹrọ ayara bi aṣa .

Taa ni olootu ijọba Sheikh Hasina?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun 1947 ni ọjọ kẹjidinlọgbọn oṣu kẹsan an nmi wọn Sheikh Hasina, to si jẹ pe oun ni olootu ijọba kẹwaa ti yoo jẹ lorilẹede Bangladesh.
O kọkọ di olootu ijọba ni ọdun 1996 ti ti wọ ọdun 2001.
O pada si ipo naa ni ọdun 2009 titi wọ ọdun 2024.
Baba Sheikh Hasina ni Aarẹ akọkọ lorilẹede Bangladesh.
O ti le logun ọdun ti Sheikh Hasina ti wa ni ipo naa, ti jẹ pe oun lo pẹ ju ninu itan orilẹede naa.















