Èyí làwọn àwòrán tó jojú-ń-gbèsè níbi ọdún Osun Osogbo ọdún 2024

Arabinrin kan pẹlu ẹwa ẹfun kikun lara rẹ
Àkọlé àwòrán, Arabinrin kan pẹlu ẹwa ẹfun kikun loju rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Awọn arabinrin meji pẹlu ẹwa ẹfun kikun loju wọn
Àkọlé àwòrán, Awọn arabinrin meji pẹlu ẹwa ẹfun kikun loju wọn.
Aarẹ na kakanfo, Iba Gani Adams atawọn alejo nibi ọdun Osogbo
Àkọlé àwòrán, Aarẹ na kakanfo, Iba Gani Adams atawọn alejo nibi ọdun Osogbo
Ataọja ti ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Oyetunji atawọn olori rẹ meji nibi ajọdun Ọṣun Osogbo
Àkọlé àwòrán, Ataọja ti ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Oyetunji atawọn olori rẹ meji nibi ajọdun Ọṣun Osogbo.
Ataọja ti ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Oyetunji atawọn olori rẹ nibi ajọdun Ọṣun Osogbo.
Àkọlé àwòrán, Ataọja ti ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Oyetunji atawọn olori rẹ nibi ajọdun Ọṣun Osogbo.
Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun
Àkọlé àwòrán, Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun.
Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun pẹlu awọn onilu niwaju rẹ
Àkọlé àwòrán, Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun pẹlu awọn onilu niwaju rẹ.
Awọn Ọlọdun iṣẹṣẹ nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn Ọlọdun iṣẹṣẹ nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Awọn alejo nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn alejo nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Awọn alejo nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn alejo nibi ọdun Ọṣun oṣogbo.
Awọn alejo lati oke okun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn alejo lati oke okun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo.
Awọn oniṣẹṣe nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn oniṣẹṣe nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo.
Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo.
Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan leti odo Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Awọn alejo nibi Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn alejo nibi Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo.
Awọn ohun iṣẹmbaye kan nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn ohun iṣẹmbaye kan nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun
Àkọlé àwòrán, Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun..
Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun.
Àkọlé àwòrán, Arugba n ru igba lọ si oju odo Ọṣun.
Yeye Ọṣun ati ikọ rẹ n lọ si ojubọ Ọṣun loju odo Ọṣun.
Àkọlé àwòrán, Yeye Ọṣun ati ikọ rẹ n lọ si ojubọ Ọṣun loju odo Ọṣun.
Awọn alejo nibi Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn alejo nibi Ọṣun nibi ọdun Ọṣun oṣogbo.
Mọ̀ sí i nípa Arugbá, omidan ọdún Ọṣun Osogbo ̀ati èèwọ̀ rẹ̀
Aworan Arugba Osun Osogbo

Bi ọdun Ọṣun Osogbo ṣe jẹ pataki to, to si jẹ ọdun ti awọn eeyan n ti n oke okun waa ṣe nipinlẹ Ọṣun, abala kan wa nibẹ ti ko gbọdọ ma waye, eyi ni abala Omidan to n ru igba Oriṣa Ọṣun Osogbo.

Ọmọbinrin ti ko ti i mọ ọkunrin lo maa n ru igba Ọṣun Osogbo, idile ọba lo si ti gbọdọ wa.

Mimọ,ai ni abawọn ati funfun nẹnẹ ni Orisa Ọṣun funra rẹ duro fun, eyi lo si fa a to fi jẹ pe ọmọge ti ko mọ ọkunrin lo maa n ru igba Ọṣun.

Ṣugbọn ta a ni Arugba? Ki ni itumọ igba riru? Ki lo duro fun? Eewọ wo ni eni to fẹẹ rugba ni lati pamọ? Alaye ree bi BBC ṣe wadii rẹ finni-finni.

Ta a ni Arugbá?

Aworan awon eeyan nibi odun Osun osogbo
Àkọlé àwòrán, Aworan awon eeayn nibi ayeye odun Osun osogbo

Aṣoju Ọṣun Osogbo ni Arugba, oun ni yoo ru igba nla kan ti wọn ṣe ipese ọlọkan-o-jọkan sinu rẹ, ọpọ eeyan yoo si tẹle e lẹyin.

Gbogbo eeyan to ba ẹdun ọkan wa sibi ọdun naa yoo maa fi iṣẹ wọn ranṣẹ si Ọṣun nipasẹ Arugba,nitori wọn ti ri i bii oriṣa lasiko to ru igba naa. Ki i ṣe eeyan lasan mọ.

Bi wọn ba fẹẹ mura fun Arugba, wọn yoo farabalẹ wa aṣọ nla to yẹ ọmọ ile ọba fun un ni. Awọn nnkan ẹṣọ alarabara ni wọn yoo si fi ṣe e lọṣọọ kari ara.

Oriṣa to fẹran oge to si gbọ faari ni Ọṣun funra rẹ, eyi lo fa a to fi jẹ ẹṣọ rẹpẹtẹ ni wọn maa n ṣe si ara Arugba o to n ṣoju Ọṣun.

Bi Arugba ko ṣe ti i mọ ọkunrin, ti ko labawọn, jẹ ohun kan ti Ọṣun funra rẹ nifẹẹ si.

Bi Arugba ṣe n ru igba naa ni wọn yoo maa fi ọ̀wọ̀ Ọṣun wọ ọ.

Igbagbọ awọn eeyan ni pe bi Arugba ṣe n gbe ipese de odo Ọṣun, oriṣa naa ti gba ohun ti awọn fẹ, yoo si da awọn lohun ẹdun ọkan awọn.

Igba lasan kọ ni Arugba n ru bi iwadii ṣe fidi ẹ mulẹ, Oriṣa Ọṣun funra rẹ lo fi igba naa ta awọn baba nla wọn lọrẹ l’Oṣogbo ni igba iwaṣẹ.

Bakan naa ni wọn fi Arugba to mọ tonitoni, we Maria mimọ inu Bibeli, ẹni ti abawọn kan ko si lara rẹ.

Kí ni àwọn èèwọ Arugbà?

Aworan obinrin kan nibi ayeye odun naa
Àkọlé àwòrán, Aworan obinrin kan nibi ayeye odun naa
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

*Arugba ko gbọdọ wo oju ọkunrin kankan ni gbogbo igba ti wọn ba n mura fun un lati ru igba.

Idi ni pe funfun ni Ọṣun to n ṣoju, Arugba ko si gbọdọ wo ọkunrin nitori ifẹkufẹẹ.

*Arugba ko gbọdọ ja ibale rẹ ni gbogbo asiko to ba fi n ru igba. Idi eyi ni pe Ọṣun fẹran jíjẹ́ omidan.

*Iyasọtọ kuro laarin eeyan: Bi imurasilẹ ba ti bẹrẹ fun igba riru, wọn yoo mu Arugba kuro laarin ọpọ eeyan.

Wọn maa n ṣe eyi lati jẹ ko gbaradi fun iṣẹ pataki to wa niwaju rẹ.

*Pipa aṣiri ohun to ba ri lasiko irinajo igba riru naa mọ

Omidan to ru igba gbọdọ le pa ẹnu rẹ mọ nipa irinajo ati ohun toju rẹ ba ri lasiko to ru igba.

Yiyago fun awọn ounjẹ kan.

Awọn ounjẹ kan wa ti wọn jẹ eewọ fun omidan to fẹẹ ru igba Ọṣun, wọn ko ba ilana iṣẹ to fẹẹ ṣe mu, Arugba ko si gbọdọ jẹ wọn.

O loju ibi ti Arugba le wọ: Bi wọn ba ṣe ọdun Ọṣun tan, Arugba ko ni i le wọ awọn ibi kan, afi ti wọn ba ṣe imọra to yẹ lẹyin igba to ru naa fun un.

Arugba ko gbọdọ ṣubu: Paripari eewọ Arugba ni pe ko gbọdọ ṣubu.

Iṣẹ awọn kan ti a mọ si Olose ni lati maa sọ igbesẹ omidan to ru igba naa.

Eewọ nla ni ki Arugba ṣubu pẹlu igba, ohun buruku ni wọn ni yoo maa re lu ara wọn to ba ṣẹlẹ.

Arugba ti dé ojúbọ odò Osun níbí ayẹyẹ àṣekágbá ọdún Osun Osogbo

Ọdọọdun laa ri orogbo, ọdọọdun laa ri awusa, ọdọọdun si laa ri ọmọ obi lori atẹ, amọdun ko si jinna, kẹni ma ri eebu sun jẹ.

Bẹẹ lọrọ ri pẹlu ọdun Ọṣun Ọṣogbo fun tọdun 2024, eyi to ti bẹrẹ fun bi ọsẹ kan bayii.

Ara awọn eto ti wọn fi n sami ọdun Ọṣun Ọṣogbo si ni ipejọpọ awọn arugba ni aafin Ataoja tilu Osogbo eyi ti a waye bayii.

Ni bayii, Arugba ti wa lọna irinajo rẹ si ojubọ odo Osun nibi ayẹyẹ aṣekagba ọdun Osun Osogbo ti 2024 yii.

Kabiyesi Ataoja lo kọkọ gbadura fun Arugba ki o to o bẹrẹ si ni ya awọn ibi ti arugba maa n de lọdọọdun ki o to morile ojubọ odo Osun.

Oriṣiiriṣii eto lo maa n waye laafin Ataoja ilu Osogbo, ki arugba to jade ti yoo si morile ojubọ.

Ọkan lara awọn eto yii ni gbigba alejo awọn to ti ru igba lọ si odo Osun sẹyin ni aafin Ataoja ilu Osogbo.

Aworan awọn ọlọdun Osun Osogbo

Nigba to n salaye ayẹyẹ igbalejo naa, agba ọjẹ kan nilu Osogbo salaye pe, ọna lati fi ẹmi imoore han si gbogbo awọn obinrin to ti ru igba Ọṣun sẹyin lo mu ki Kabiyesi gba wọn lalejo.

Nibi ayẹyẹ igbalejo naa to maa n waye lọdọọdun, ni awọn arugba yoo ti maa jo yika igba Ọṣun, eyi to fihan pe isẹ igba ruru ti wọn se ko ja si asan.

A gbọ pe Ifa lo maa n fa ọmọge ti o maa ru igba Ọṣun kalẹ laarin awọn ọmọbinrin ti Ataoja to wa lori oye ba bi.

Ọmọge ti ifa ba si mu yii ko gbọdọ tii mọ ọkunrin, yoo si se isẹ naa titi ti yoo fi wọ ile ọkọ ni.

O ya, ẹ jẹ ka wo bi ayẹyẹ ipejọpọ gbogbo awọn Arugba se lọ nilu Oṣogbo lasiko ọdun Ọṣun Ọṣogbo fun tọdun yii.