Ọkùnrin tó bá ajá lòpọ̀ rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he

Oríṣun àwòrán, ABC News
Ọkunrin kan to jẹ onimọ nipa sinsin eranko ọọni ti ri ẹwọn ọdun mẹwaa ati oṣu marun un he ni Australia.
Idajọ yii waye nigba ti ọkunrin ọun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an pe o n ba aja sun, ti iṣẹlẹ ọhun si ba ọpọ eeyan lẹru lorilẹede naa.
Adam Britton, onimọ nipa ẹranko lo ti siṣẹ ri pẹlu BBC ati National Geographic.
Ẹsun mẹsindinlọgọta ni wọn ka sii lẹsẹ, to gba pe oun jẹ bi ẹsun pe o n ṣe awọn ẹrankọ basubasu.
Bakan ni ileẹjọ tun ri pe o jẹ bi ẹsun nini anfani si awọn nnkan lo farajọ sise ọmọde basubasu.
Ọwọ ileẹjọ ti tẹ fọnran ti Britton ya lasiko to n se ikọlu si awọn ẹranko naa, to si gbe so ri ayelujara pẹlu ayederu orukọ.
Ọpọ eeyan lo ti kẹfin pe o ti n hu iwa yii tipẹ, ti wọn si itọsọna laipẹ yii ninu fọnran kan to gbe sita lori ayelujara.
Ọwọ tẹ Britton ni ọdun 2022 ninu oṣu kẹrin lẹyin ti wọn wadi dukia rẹ to wa ni Darwin, nibi ti wọn ti ri ọpọ ẹri lori ẹrọ ayarabiaṣa rẹ.
Nigba to n gba idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Micheal Grant sọ fun Britton pe awọn fọnran to n gbe sita ko tọna lati ma wa lori ayelujara.
Ọpọ awọn nnkan ti Britton se ni ko se gbe sita .
Bakan naa ni ile ẹjọ tun fofin de Britton lati ni eyikeyi ẹranko ni ayika rẹ
N jẹ ikọlu si ẹrank yii ti n waye tipẹ?
Wọn bi Britton ni West Yorkshire, to si dagba niluu UK ko to di pe o lọ si orilẹede Australia.
O lo Ogun ọdun ni Australia, to si n siṣẹ pẹlu awọn ọọni.
Pẹlu oye PhD rẹ ninu imọ ẹkọ zoology, o jẹ ilumọka ni ẹka to n sisẹ.
Awọn to wa ni agbegbe rẹ sọ pe o jẹ eeyan ti ko le sọrọ ẹnu rẹ tan, to si nifẹ ẹranko.
Sugbọn o jẹ eeyan nifẹ lati ba awọn ẹranko sun gẹgẹ bi ohun to wa niwaju ile ẹjọ.
O sọrọ, “Lati kekere ni mo ti ma banu jẹ, ti mo si korira eranko sugbọn mo ba ara mi wi. Ni ọdun diẹ sẹyin, ni mo tun jẹ ko jade pada, ti n ko si le da duro mọ. N ko fẹ da duro.” Eyi lo wa ninu lẹta to kọ siwaju ile ẹjọ.
“Awọn aja mi da bi mọlẹbi mi,” O sọ ninu ọrọ to fi ransẹ lori ayelujara
Ẹranko melo lo sekọlu si?
Ẹranko mejilelogoji, to si sekupa mọkandinlogoji ninu wọn gẹgẹ bii ẹri to wa ni ilẹ ẹjọ se ṣalaye
Awọn ẹi lo jẹ awọn ẹri nipa awọn nnkan to ṣe laarin oṣu mẹrindinlogun ki ọwọ to tẹ.
O n lo ọja ori ayelujara, Gumtree Australia lati ṣawari awọn eeyan ti wọn bu eeyan ni ohun ọṣin wọn nitori wọn fẹ rin irin ajo.
Britton tun n kọ awọn eeyan kan bi wọn se le sekọlu si awọn ẹranko yii, ti wọn yoo si dana sun awọn ẹri.















