Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìpàdé tó wáyé láàrin Ladoja àti Makinde

Oríṣun àwòrán, Akeem Azeez
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti bẹrẹ isinmi ranpẹ lẹnu iṣẹ, lati ẹnu isinmi yii si ni o ti ṣe abẹwo si Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan ti o tun jẹ Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Oloye Rashidi Ladoja l'Ọjọru ni ile rẹ to n bẹ ni Bodija.
Ọkan lara awọn oluranlọwọ fun Makinde, Akeem Azeez lo fi aworan ipade naa s'ori itakun ayelujara.
Lati igba ti aworan naa ti de ojutaye ni ọkanojọkan ariwisi ti n waye n lori ipade naa nitori ọpọ eeyan ni ko lero wi pe awọn mejeeji le ni nnkan kan ṣe pọ lasiko yii.
Ajọṣepọ laarin Makinde ati Ladọja pelu awọn aṣiwaju oṣelu mii jẹ ọkan pataki lara awọn igbesẹ to mu ki o wọle gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ọyọ l'ọdun 2019, ṣugbọn nigba ti yoo fi di asiko ipolongo ibo fun saa ikeji, o fẹ maa jọ wi pe ajọṣepọ laarin Gomina Makinde ati Oloye Ladọja ko danmọran mọ.
Nnkan mii to tun fi idi aigbọraẹniye naa mulẹ ni bi Makinde ṣe buwọlu atunto jijẹ Oye Olubadan ilẹ Ibadan ninu iwe ofin to tọka rẹ wi pe Oloye ti ko ba gba ade tẹlẹri gẹgẹ bii ọkan awọn Ọba kekeeke nilẹ Ibadan ko ni le jẹ Oye Olubadan to ba di asiko tirẹ(to si jẹ wi pe Oloye Ladọja nikan ni ko gba Ade awọn Ọba kekeeke nilẹ Ibadan).
Oloye Rashidi Ladọja pada kede wi pe oun ṣetan lati gba Ade isaaju naa ki o le yẹ ni ẹni ti Oye Olubadan ilẹ Ibadan tọ si, ṣugbọn ọpọlọpọ eeyan lo ro wi pe Makinde fi ofin naa dẹyẹ si Ladọja ni.
Bi a ṣe wa dede ri awọn mejeeji pọ l'Ọjọru lo mu ki BBC Yoruba kan si Oloye Ladọja.
Ọkan lara awọn oluranlọwọ Oloye agba naa, Mutiu Oluwatoin ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe lootọ ni Makinde ṣe abẹwo si ile Oloye Ladọja ti wọn si di mọ ara wọn nita ko to di pe wọn wọ iyẹwu lọ sọ ọrọ baba ati ọmọ.
Ẹnikẹni ko si mọ ohun ti wọn jọ ba ara wọn sọ ninu ile.
Oluwatoyin ni, "ipade laarin ọmọ ati baba ni, inu ile ni wọn ti sọrọ, a ko dẹ gbọ abọ.
A ṣaa mọ pe awọn mejeeji jọ di mọ ara, wọn jọ rẹrin nigba ti wọn de."















