Wo orílẹ́èdè táwọn obìnrin gbọdọ̀ gba àṣẹ lọ́wọ́ ọkọ wọn kí wọ́n tó lè rí iṣẹ́ gbà

Aranṣọ obinrin Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ipenija tawọn oninrin n koju nipa iṣẹ ṣiṣe ni Iran pọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

“Nibi ifọrọwanilẹnuwo lati gba iṣẹ, wọn sọ pe ki n mu iwe aṣẹ afọwọkọ ti ọkọ mi fọwọ kọ wa lati le fidi idaniloju han pe ọkọ mi gba mi laaye lati ṣiṣẹ,” Neda, to ni iwe ẹri ipele ẹkọ giga keji (masters) ninu ẹka ikẹkọọ nipa imọ ẹrọ ti epo rọbii ati afẹfẹ gaasi (oil and gas engineering) ni Iran.

O ni oriṣiriṣi irẹnisilẹ ati idojutini loun ti ba pade.

“Mo sọ fun wọn pe agbalagba ni mi, mo si ni ẹtọ si igbesẹ ti mo ba gbe.”

Iriri rẹ kii ti ṣe ti adagbe. Labẹ ofin, awọn obinrin ti wọn ba wa nile ọkọ gbọdọ gba iwe aṣẹ lọwọ ọkọ wọn ko to di pe wọn lọ ṣiṣẹ - ọkan lara awọn ipenija ti wọn n doju kọ ko to di pe wọn wọ ọja iṣẹ tabi okoowo.

Abajade iwadii ọdun 2024 lati banki agbaye gbe Iran sori iwọn ipele awọn orileede to ku diẹ kaato nigba to di ọrọ ọkunrin ati obinrin labẹ ofin, paapaa lẹka iṣẹ ati okoowo (Yemen ati West Bank ati Gaza lo wa nisalẹ patapata).

Bakan naa ni awọn akọsilẹ agbeyẹwo miran. Gẹgẹ bi ajọ akọsilẹ World Economic Forum ti iwadii ọdun 2024 ti wọn pe ni Global Gender Gap, Iran wa ni isalẹ patapata laarin awọn orileede 146.

Nigba to jẹ pe ida aadọta obinrin lawọn ti wọn kẹkọọjade fasiti lorileede naa, sibẹ, ida mejila ni awọn to wa lẹnu iṣẹ, gẹgẹ bi akọsilẹ iwadii ọdun 2023.

Ofin iyatọ laarin akọ ati abo pẹlu itankalẹ iwa igbero lati fipabanilopọ pẹlu wiwo aladun ibalalopọ lori awọn obinrin ati akikanju wọn ti jẹ ki agbegbe iṣẹ jẹ eyi lodi si awọn obinrin.

Graphic

Pupọ awọn to ba BBC sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ yii sọ pe wọn ko kọbi ara si wọn gẹgẹ bi ẹni to mọ nipa nnkan ti wọn n ṣe nigba ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ.

“Ọpọ ilana 'ọlọkan-o-jọ-kan lo n di awọn obinrin lọna lati ṣiṣẹ lorileede Iran”, Nadereh Chamlou, oludamọran agba tẹlẹ nile ifowopamọ agbaye lo sọ eyi.

Ms Chamlou ssọ pe awọn ileeṣẹ nla-nla ko ni ilana eto iṣẹ to tobi, ati pe ila to pọ lo wa nigba to ba di ọrọ iṣẹ fun ọkunrin ati obinrin ni Iran.

O ba ofin... ati aṣa mu

Awọn ọkunrin mọ pe awọn le da iyawo awọn duro lẹnu iṣẹ labẹ ofin, awọn kan si n lo anfaani ofin yii.

Olokoowo ọmọ Iran nni, Saeed sọ fun BBC pe nigba kan, “mo ri ọkunrin kan to jawọ inu ọfiisi mi, to si n fi irin kan, to si n pariwo wi pe 'talo fun un yin laṣẹ lati gba iyawo mi si iṣẹ?’’’.

O sọ pe o ti wa di dandan foun lati maa beere iwe aṣẹ awọn ọkọ wọn nigba toun ba ti fẹẹ gba obinrin si iṣẹ oun.

Razieh, to jẹ ọdọmọde akọṣẹmọṣẹ toun n ṣiṣẹ nileeṣẹ aladani kan naa ranti awọn ohun to ṣẹlẹ nibi to ti n ṣiṣẹ, to si loun ko le gbagbe igba ti ọkunrin kan ja wọ inu ileeṣẹ wọn, to si sọ fun aladani wọn wi pe: ‘Mi o fẹ ki iyawo mi ṣiṣẹ nibi’.

Razieh sọ pe ọga awọn ni lati sọ fun obinrin naa, ẹni to jẹ oluṣori owo agba “lati maa lọ sile, ko si lọ yanju pẹlu ọkọ rẹ. lai jẹ bẹẹ, yoo ni lati kọwe fi iṣẹ silẹ, eyi to pada ṣe.”

Ọdọbinrin Iran to n ṣiṣẹ lori kọmputa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdọbinrin Iran to n ṣiṣẹ lori kọmputa

Nadereh Chamlou eka ofin yii tun ti jẹ ki awọn ileeṣẹ dẹkun lati maa gba awọn ọdọbinrin si iṣẹ, pẹlu bo ṣe ni awọn agbanisiṣẹ ko fẹẹ maa “padanu asiko lati maa kọ wọn niṣẹ, ko wa di pe ọkọ wọn maa le wọn kuro lẹnu iṣẹ naa”.

Ati pe sibẹ, bi wọn ba gba wọn si iṣẹ lẹyin ti wọn ba ba mọlẹbi ati ọkọ wọn ja lati ṣiṣẹ, awọn obinrin yoo tun wọnu iṣẹ ti ẹlẹyamẹya iṣẹ ti wa, eyi to ni atilẹyin ofin.

Awọn obinrin Iran Iran nile iṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin Iran Iran nile iṣẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn ofin naa lo wa ni abala 1105 ninu iwe ofin orileede Isilaamu (Islamic Republic’s Civil Code), eyi to ṣapejuwe ọkọ gẹgẹ bi olori ẹbi ati olupese inu ile. Eyi lo fidi rẹ mulẹ pe awọn lo ni anfaani si iṣẹ ju obinrin lọ, awọn ti wọn to tun jẹ pe o niye owo oṣu ti wọn le gba, to yatọ si ti ọkunrin nigba ti wọn ba fun wọn ni iṣẹ.

Raz, to ti paarọ iṣẹ rẹ sọ pe gbogbo ibi toun ti ṣiṣẹ lo jẹ pe iṣẹ obinrin ni wọn maa n tete fi silẹ.

“Ibi ti mo ti ṣiṣẹ gbẹyin, nigba ti atunto waye, o fẹẹ jẹ pe gbogbo awọn obinrin to wa nibẹ ni wọn sọ pe ki wọn maa lọ sile,” o sọ eyi.

Obinrin miran ti ko fẹẹ da orukọ ara rẹ sọ fun BBC pe, oun finufẹdọ fi iṣẹ silẹ latiu duro sile ni “nitori mo mọ pe mi o ni gba igbega lẹnu iṣẹ”.

“Niwọn igba ti awọn ọkunrin ba ṣi wa nilẹ, koda bi wọn ko ba tiẹ yege, wọn ko le mu mi mọ awọn to maa gba igbega tabi afikun owo oṣu. Bi ẹni to n fi asiko ṣofo lasan lo ri,” O fi kun ọrọ rẹ.

Wi pe wọn ko ri awọn obinrin gẹgẹ bi olutọju mọlẹbi ati olupese ninu ile, boya wọn yoo yege fun awọn anfaani ati ajẹmọnu.

Lọpọ igba, bi wọn ba yẹ “awọn ẹtọ ti wọn ri gba lawọn asiko ti wọn fi wa lẹnu iṣẹ ko le ṣe fun awọn mọlẹbi wọn, awọn ẹtọ bii owo ifẹyinti”, Ms Chamlou lo sọ bẹẹ.

“Fun idi eyi, wọn n mu adinku ba iye ti awọn obinirin n gba, ti wọn si le mu lọ fun mọlẹbi wọn,” o fi kun ọrọ rẹ.

Awọn obinrin gbọdọ wọ hijaabu lẹnu iṣẹ ni Iranf Tehran) overlooking the city of Tehran, 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin gbọdọ wọ hijaabu lẹnu iṣẹ ni Iran

Sepideh ni iwe ẹri 'master’s' rẹ ni fasiti Tehran, bẹẹ lo tun n kẹkọọ nibẹ pẹlu awọn iṣẹ agbelẹrọ rẹ, ṣugbọn lati bi ọdun diẹ sẹyin ni ko ti ṣiṣẹ mọ.

“Lẹyin ayẹyẹ ikẹkọọjade, mo ro pe emi naa le maa ri owo bi awọn ọkunrin yooku ti mo mọ, ṣugbọn awọn ilana ati eto to wa nilẹ nipa igbe aye, oṣelu ko faaye silẹ fun ipele ti obinrin lero wi pe oun le de,” Sepideh sọ fun BBC.

Ijaabu to pọn dandan jẹ eyi ti wọn ti fẹhonuhan si lọdun meji sẹyin ni Iran, to si tun jẹ akori ti awọn eeyan fi n sọrọ ni gbogbo igba lorileede naa.

Ofin yii ko fi aaye gba obinrin lati ṣe oniruuru iṣẹ, paapaa iṣẹ ijọba lati ṣe, ati paapaa awọn obinrin ti wọn ko fẹran lati maa wọ ijaabu.

Ohun to ko si

‘Ni Iran, ohun kan wa ti wọn n pe ni aarin to sọnu (missing middle),’ Nadereh Chamlou lo sọ eyi, bẹẹ lo tun tẹsiwaju lati ṣalaye pe nnkan toun tunmọ si ni “awọn ti ọpọ ori wọn wa ni ọdọ, awọn to kẹkọọ de aarin meji; awọn kẹkọọ de ile-ẹkọ girama, awọn obinrin ti wọn wa laarin meji, ṣugbọn ti wọn ko ṣiṣẹ.”

“Aṣẹ labẹ ofin ti awọn ọkọ nilo lati fi silẹ fun awọn iyawo lati ṣiṣẹ, ati pe obinrin ko gbọdọ kọja ọdun marundinlọgọta ko to fẹyinti ni Iran, eyi to jẹ pe lawọn orileede miran, wọn ṣi wa lénu iṣẹ”.

Awọn obinrin to ba jẹ adari ileeṣẹ maa n saba ran obinrin ẹgbẹ wọn lọwọ er luxury pastry company in Tehran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin to ba jẹ adari ileeṣẹ maa n saba ran obinrin ẹgbẹ wọn lọwọ

Wọn ya eto ọrọ aje Iran ni arọ nipa aisi otitọ ati iwa ajẹbanu. Iwadii ajọ IMF tọka sii wi pe idagbasoke maa n deba eto ọrọ aje nigba ti awọn obinrin ba ni ipa ti wọn n ko, to si ni bi iye awọn obinrin to n ṣiṣẹ ba to ti awọn ọkunrin, idagbasoke maa wa pẹlu ida ogoji.

Ninu erongba Nadereh Chamlou, ko si ohunkohun to le mu ki wọn yi erongba pada lati le jẹ ki awọn obinrin naa maa ṣiṣẹ ni Iran.

Ṣugbọn o nigbagbọ pe awọn obinrin ni Iran ti bẹrẹ igbesẹ ara wọn lati ṣi iṣẹ funra wọn, lati le jẹ ki awọn naa wa ninu ọja okoowo funra wọn.

“Lara awọn ọgbọn iṣẹ naa ni ti idana lori ayelujara, ni awọn obinrin ti gbe dide,” o ṣalaye, pẹlu bo ṣe ni oun ri awọn okoowo aladani to jẹ pe awọn obinrin ni wọn da a silẹ.