A kò mọ ohunkóhun nípa ìkọlù sí olú iléeṣẹ́ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC l'Abuja - Àjọ DSS

Aworan DSS ati Joe Ajaero

Oríṣun àwòrán, Screenshots

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lorileede Naijiria, DSS ti sọ pe awọn ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan awọn nipa wi pe awọn yabo ọfiisi ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ l’Abuja.

L’Ọjọbọ to kọja yii ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria, DSS fi ẹsun kan ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wi pe wọn digun wọ olu ileeṣẹ wọn, ti wọn si ji ọpọlọpọ iwe ati atẹjade to ṣe pataki salọ.

DSS sọ pe ko si otitọ kankan ni ẹsun ti NLC fi kan awọn, nitori pe awọn ṣe iru iṣẹ to jẹẹ rara.

Ninu ọrọ ti agbẹnusọ ileeṣẹ DSS, Peter Afunanya fi sita, o sọ pe “Ẹ kaarọ ẹyin ọrẹ wa. Ẹ dakun, a fẹ ki ẹ mọ wi pe ileeṣẹ DSS ko ṣiṣẹ kankan ni ọfiisi NLC l’Abuja.”

Kí ló mú kí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ààbò yá wọ olú ọ́ọ́fìsì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC l'Abuja?

Ileese NLC Abuja

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, ẹka ti NLC ti sọ pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo kan ti wọn gbe awọn nnkan ija oloro dani ti ya wọn ileeṣẹ wọn.

NLC ninu atẹjade ti Kọmureedi Benson Upah to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ naa gbe jade loni Ọjọbọ lo ti sọ pe nnkan bi agogo mẹjọ aabọ alẹ ni awọn agbebọn naa yawọ olu ileeṣẹ wọn to wa niluu Abuja.

Ọpọlọpọ iwe ati atẹjade ni wọn ko lọ nibẹ, ti wọn si fẹsun kan awọn oṣiṣẹ aabo agbebọn naa pe wọn n wa awọn irinṣẹ ifẹhonuhan to n lọ lọwọ kaakiri Naijiria.

“Wọn ja inu ile ikowepamọ si wa to wa ni aja keji, wọn si ko ọpọlọpọ iwe ati atẹjade to le ni ọgọrun kan lọ. Awọn to wa naa sọ pe awọn n wa awọn irinṣẹ ti wọn n lo fun ifẹhonuhan #EndBadGoveranance to n lọ lọwọ.”

Ikọlu yii lo waye lẹyin ọjọ kẹfa ti iwọde naa ti bẹrẹ, ti ko si tii pari ni ẹgbẹ NLC ti bu ẹnu atẹ lu.

NLC ti wa sọ pe awọn ko nilo oṣiṣẹ eleto aabo kankan mọ ni olu ileeṣẹ wọn, titi digba ti awọn yoo fi tun ero wọn pa.

“Ẹgbẹ NLC bu ẹnu atẹ lu eto aabo ati awọn oṣiṣẹ aabo orileede Naijiria. Awọn eleto aabo ọhun ko ṣafihan iwe aṣẹ yoowu lati yabo ileeṣẹ wa lasiko ti ko tọna ni alẹ.

“Koda, lasiko iṣakoso awọn ologun, ko sẹni to yabo ileeṣẹ NLC, ki wọn si wọle lati ko ẹru lọ. Oni yii jẹ ọjọ ti ko dara fun eto oṣelu awa-ara-wa.”

Kinni ajọ Amnesty International sọ lori iṣẹlẹ naa?

Ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan lagbaye ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ti awọn eleto aabo ṣe lọ si ileeṣẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ NLC to wa niluu Abuja.

Ninu atẹjade ti alakoso ajọ naa lorileede Naijiria, Isa Sanusi gbe jade l’Ọjọbọ lo ti sọ pe nipa iṣiro ni wọn fi ṣe ikọlu ọhun lati dunkooko mọ ẹgbẹ naa.

Amnesty International sọ pe ọrọ eto aabo awọn alakoso ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC jẹ awọn logun pupọ, ti awọn ko si le fọwọ lẹran nipa ohun to ṣẹlẹ yii.

“Eto aabo awọn adari ẹgbẹ NLC jẹ wa logun. Labẹ agbekalẹ ẹtọ ọmọniyan lagbaye, wọn ko le ṣe ikọlu si ẹgbẹ oṣiṣẹ nipa wi pe wọn da si ohun to n lọ.

“Labẹ ofin ẹtọ ọmọniyan, kii ṣe ojuṣe Naijiria nikan ni lati bọwọ fun ẹtọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, bi ko ṣe bibọwọ fun ẹtọ ifiyajẹni lai lẹtọọ.”

A ko kọlu ọọfisi NLC - DSS

DSS

Oríṣun àwòrán, DSS/X

Ẹwẹ, ajọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS, ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ọrọ naa.

Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ ni DSS ti sọrọ naa lọjọbọ.

O ni "a fẹ ki ẹ mọ pe DSS ko lọ si ọọfisi NLC fun iṣẹ kankan l'Abuja."