Owó tí iye rẹ̀ tó ₦3b ni a pàdánù lásìkò tí ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé – Àwọn oníṣòwò ẹkùn àríwá Nàìjíríà

Awọn ipinlẹ kan ni Ariwa Naijiria ti bẹrẹ si n dẹwọ ofin igbele ti wọn kede latari iwọde to bẹ silẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ.
Amọ titi di asiko yii lawọn eeyan ipinlẹ naa ṣi n ni imọlara ofin konile-o-gbele naa latari bi awọn oniṣọwo ṣe gbe ṣọọbu wọn tipa.
Iwọde to fa igbele ọhun ko ṣẹyin ọwọngogo to gbode ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe ilẹ Yoruba ati ilẹ Igbo ni ọpọ awọn to n ṣagbtẹru iwọde naa ti wa, ilẹ awọn Hausa to wa ni Ariwa ni ifẹhonunhan ọhun ti milẹ titi julọ.
Lara awọn ipinlẹ ti ijọba ti kede ofin igbele ni Kano, Yobe, Kaduna ati Jigawa latari awọn togbodiyan to bẹ silẹ lawọn ipinlẹ ọhun.
Awọn ipinlẹ ti ofin konile-o-gbele ṣi wa lode

Yobe: Lati aago mẹfa irọlẹ si mẹfa aarọ ni igbele nibẹ.
Kano: Ijọba Kano sọ pe ki awọn eeyan gbele wọn lati aago mẹfa irọlẹ si mẹfa aarọ.
Kaduna: Aago mẹjọ aarọ ni ofin ibele yoo dẹwo ti yoo tun bẹrẹ lati aagọ mẹfa irọlẹ.
Plateau: Aago mẹfa irọlẹ si aago mejila ọjọ keji ni igbele ni ipinlẹ Plateau.
Jigawa: Gomina Hamisu Muhammad Gumel ti dẹwọ igbele naa ni ijọba ibilẹ mọkandinlogun, amọ lawọn ijọba ibilẹ mẹjọ to ku, aago mẹfa irọlẹ ni igbele yoo bẹrẹ si aago marun un afẹmọju.
Awọn ijọba ibilẹ naa ni Dutse, Gumel, Hadejia, Kazaure, Roni, Babura, Birnin Kudu ati Kiyawa.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
“Ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira ni a padanu lasiko igbele”
Alaga ọja Singa, Musa Ibrahim sọ pe owo nla lawọn ọlọja padanu lasiko igbele ni Kano.
O ṣalaye pe ni ṣọọbu kan ṣoṣo, eeyan kan le pa owo to le ni N300m, irufẹ awọn ṣọọbu bẹẹ si pọ ninu ọja ọhun.
O ni “a padanu owo to kọja biliọnu meji si mẹta laarin ọjọ perete ti a ko fi wa si ọja.
“Gbogbo wa ni ọrọ naa kan ninu ọja latari pe ojojumọ la n ta ọja.”
Musa ni owo ti awọn padanu kọja ki awọn janduku ji ọja wọn ko lasiko iwọde.
O ni awọn gbọ pe awọn kan fẹ wa ja ṣọọbu wọn amọ wọn ko le ja awọn ṣọọbu naa latari igbele ti ijọba kede.












