₦570bn tí Ààrẹ Tinubu láwọn ìpínlẹ̀ gbà kíì ṣe láti tán ìṣẹ́ aráàlú, ẹ̀yáwó ni - Makinde ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti sọrọ sita wi pe ijọba oun ko gba ninu owo iranwọ oni biliọnu lọna aadọrinlelẹẹdẹgbẹta (₦570bn) kankan lọwọ ijọba apapọ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.
Makinde lo sọrọ yii ninu ọrọ to gbe soju opo ‘X’ ati ‘Facebook’ rẹ l’Ọjọbọ, ọsẹ yii.
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lasiko to n ba awọn araalu sọrọ lori iwọde #EndBadGovernance to n lọ kaakiri Naijiria lọwọ kede pe oun ti fun awọn ipinlẹ mẹtadionlogoji orileede naa ni 570bn lati fi gbogun ti ebi, iṣẹ ati oṣi to n ba araalu finra.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Tinubu tun sọ pe tiriliọnu meji naira ni ijọba Naijiria n na loṣooṣu lati fi gbe epo rọbii ati disu, to fi mọ afẹfẹ gaasi wọle.
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun jẹ ko di mimọ pe tiriliọnu mẹsan le diẹ (₦9.1tn) naira ni owo ti ijọba pa wọle laarin oṣu mẹfa akọkọ lọdun 2024, to si ni aṣeyọri nla ni eyi jẹ si iye ti wọn n ri lasiko ijọba to kọja.
Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti Gomina Seyi Makinde buwọ lu, eyi to gbe soju opo ‘X’ rẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe oun ko mọ nipa owo iranwọ (Grant) ti aarẹ sọ.
“Ninu lẹta iroyin mi lalẹ oni, mo n dahun si ibeere awọn ọmọ ipinlẹ Oyo nipa owo iranwọ ‘N570b’ tijọba apapọ sọ pe awọn fun awọn ipinlẹ lati gbọgun ti iṣẹ ati oṣi.
“Fun idi eyi, lati dahun si ọrọ naa, ijọba apapọ ko fun ipinlẹ Oyo ni owo kankan. A gba awọn owo kan (N5.98b fun igba akọkọ ati N822m fun igba keji), a si fi dokoowo si ọna mẹta ninu agbekalẹ NG-CARES, lara eyi to jẹ pe a pin fawọn agbẹ nipinlẹ wa.
“Koda, nigba ti banki agbaye ri ilana ati agbekalẹ wa lori ọna ti a gba gbe eto pinpin owo naa kalẹ nipa iforukọsilẹ awọn to jẹ anfaani, awọn naa bẹrẹ ilana NG-CARES ti wa.”
Makinde lo sọrọ yii lori awuyewuye to n lọ kaakiri igboro Naijiria nipa ifẹhonuhan ti awọn araalu n ṣe lori ebi, iṣẹ ati oṣi to n ba araalu finra.















