Ìjọba Nàíjíríà dáwọ́ títa ìrẹsì dúró fún àwọn òṣìṣẹ́

Ijọba orileede Naijiria ti sọ pe awọn ti dawọ eto tita irẹsi oni aadọta kilogiraamu (50kg) fun awọn oṣiṣẹ duro lai nidi.
Ileeṣẹ to n ri sọrọ eto akanṣe iṣẹ ni Naijiria lo gbe atẹjade naa sita fawọn ileeṣẹ ijọba kaakiri l’Ọjọbọ, ọsẹ yii.
Ṣaaju ni ijọba apapọ ti sọ pe ki awọn oṣiṣẹ ijọba to ba nifẹ si irẹsi ọhun lọ fi orukọ silẹ lawọn ẹka ileeṣẹ ti wọn gbe eto ọhun sabẹ rẹ.
Atẹjade miran to jade lọjọ keji, oṣu kẹjọ, ọdun yii, eyi ti alakoso ileṣẹ to n ri sọrọ awọn enitan, Aderonke Jaiyesinmi buwọ lu ko ṣalaye idi pataki ti wọn fi gbe igbesẹ ọhun.
Ko si ẹni to le sọ pato boya wọn ti fopin si tita irẹsi naa patapata, tabi pe wọn kan daa duro fungba diẹ ni.
Atẹjade ọhun sọ pe “Wọn ti dari mi lati pin atẹjade yii si ileeṣẹ wa lọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2024, lori akọle to wa loke lati jẹ ko di mimọ fun un yin pe a ti da eto naa duro.
“Ẹkunrẹrẹ alaye la maa sọ fun un yin to ba ya. Ẹ dakun, ẹ jẹ ki gbogbo awọn oṣiṣẹ yin mọ nipa igbesẹ yii fun itọni to tọ.”
Ṣaaju asiko yii, ileeṣẹ ijọba naa ti sọ fawọn oṣiṣẹ lati fi orukọ silẹ pẹlu fọọmu ori ayelujara (Google form) ti wọn fi ranṣẹ sawọn olori awọn oṣiṣẹ kaakiri, ki wọn si fi ranṣẹ si alakoso ileeṣẹ to n sọrọ ọmọniyan.
Sisan owo ati pinpin awọn irẹsi ọhun la gbọ pe awọn ileeṣẹ ti wọn gbe eto ọhun le lọwọ yoo ṣeto rẹ
Ẹgbẹrun lọna ogoji naira ni ijọba Naijiria sọ pe awọn yoo ta baagi irẹsi kan to jẹ aadọta kilogiraamu
Minisita fọrọ iroyin ati ilanilọyẹ, Muhammed Idris sọ pe lara awọn igbesẹ ijọba Tinubu ni lati mu igbe aye rọrun fawọn araalu.















