Nǹkan bíi ₦700b làwọn èèyàn san gẹ́gẹ́ bíi rìbá lọ́dún 2023 – ICPC

bribe

Oríṣun àwòrán, Meta

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n gbodun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, ICPC ti sọ pe owo ti iye rẹ le ni aadọrin biliọnu naira lawọn eeyan san gẹgẹ bii riba lọdun 2023.

Alaga ajọ naa, Musa Aliyu lo sọ bẹẹ nibi ipade kan to waye ni fasiti Ahmadu Bello, to wa niluu Zaria, ipinlẹ Kaduna.

Aliyu sọ pe iwa ajẹbanu ni agba iṣoro to n dojukọ Naijiria gẹgẹ bii orilẹede, ati pe ọrọ naa nilo ki gbogbo araalu gbogun ti i.

O mẹnuba atẹjade ajọ NBS kan to kede pe iwa ajẹbanu lo wa nipo kẹrin iṣoro to n ba Naijiria finra.

Amọ pẹlu gbogbo rẹ, o ni ireti ṣi wa fun Naijiria latari bi awọn araalu ṣe n fi iṣẹlẹ riba to awọn leti.

O ni “a n ṣe awọn aṣeyọri kan latari bi awọn araalu ṣe n fi ẹsun riba to wa leti, eyii to le si lati 3.6% lọdun 2019 si 8.6 lọdun 2023.

“Eyii n fihan pe awọn eeyan mọ bi nnkan ṣe n lọ, wọn si ti ṣetan lati gbogun ti iwa ibajẹ.

“Iwa ajẹbanu n ṣakoba fun ẹtọ araalu, o si n mu aidọgba ati irẹjẹ lọwọ.”

“Ajọ ICPC si ṣetan lati ri daju pe ẹnikẹni ko rẹ ẹnkeji jẹ, bẹẹ la o si ri daju pe idajọ idodo wa laarin ilu.

O fi kun pe fifi ibalopọ lọ akẹkọọ lọna aitọ jẹ ohun buburu mii to gbilẹ lawọn ile ẹkọ giga Naijiria.

Nigba to n mẹnuba atẹjade ajọ World Bank ti ọdun 2018, o ni ida 70% awọn akẹkọọbirin nile ẹkọ giga Naijiria ni awọn olukọ n fi ibalopọ lọ lọna ti ko ba ofin mu.

Alaga ICPC ọhun tun tẹnumọ aṣilo ipo gẹgẹ bii iwa to buru jai, eyii to gbọdọ di oun igbagbe lawujọ ni Naijiria.

O pari ọrọ rẹ pe ajọ naa ti ṣetan lati ilu fọ ilu mọ pẹlu atilẹyin gbogbo ọmo Naijiria.