Ta ni Issa Hayatou Ààrẹ àjọ CAF tẹ́lẹ̀rí tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 77?

Issa Hayatou

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ tẹlẹri fun ajọ to n ṣakoso eto ere ibọọlu afẹsẹgba nilẹ Afrika CAF to pẹ julọ lori ipo, Issa Hayatou ti jade laye.

Issa Hayatou lo jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77) niluu Paris.

Ọdun mọkandinlọgbọn ni Hayatou lori ipo gẹgẹ bi aarẹ CAF.

Ọdun 1988 ni oloogbe naa di Aarẹ CAF, to si fi ipo naa silẹ lọdun 2017.

Hayatou wa lara igbimọ iṣakoso ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lagbaye, FIFA, to si di ipo nla mu nibẹ.

Ọkan lara awọn ọmọ igbimọ ajọ kan lorileede Switzerland ti a mọ si Fifa council ni Hayatou, to si wa nibẹ laarin ọdun 1990 si ọdun 2017.

Lọdun 2015 ni wọn fi oloogbe ọhun jẹ aarẹ fidihẹ fun ajọ FIFA, lẹyin ti wọn sọ fun Sepp Blatter to jẹ aarẹ tẹlẹ pe ko lọ rọkun nile.

Hayatou lo ṣeto idibo alaafia to gbe Aarẹ Gianni Infantino wọle lọdun 2016.

Aarẹ Gianni Infantino ti wa fi atẹjade ibanikẹdun si mọlẹbi oloogbe naa, to si ṣapejuwe Hayatou gẹgẹ bi akikanju to lo igba ewe rẹ daadaa lẹka ere idaraya.

Ninu ọrọ ti Infantino kọ soju opo Instagram rẹ, o ni “O bani lọkan jẹ lati gbọ ipapoda aarẹ CAF tẹlẹ, aarẹ fidihẹ tẹlẹ fun FIFA, igbakeji aarẹ FIFA tẹlẹ ati ọmọ igbimọ iṣakoso FIFA, Issa Hayatou.”

“Akikanju to ni itara fun ere idaraya, o si fi gbogbo aye rẹ jin fun ere idaraya.

“Lorukọ ajọ FIFA, mo fi ibanikẹdun yi ranṣẹ si mọlẹbi, ọrẹ ati awọn alabaṣiṣẹ pọ rẹ tẹlẹ ati gbogbo awọn to mọ ọn. Sun re o,” Infantino lo kọ ọ bẹẹ.

Ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2021, ajọ FIFA fi ofin de Hayatou fun ọdun kan gbako, lori ẹsun wi pe o tapa si ofin nipa bibuwọlu iwe ibaṣepọ agbabọọlu to ga julọ nilẹ Afrika pẹlu ileeṣẹ ileeṣẹ iroyin ilẹ Faranse, Lagardere lọdun 2016.

Inu oṣu keji, ọdun to tẹle ni ile ẹjọ wọgile iwe ẹsun naa.

Mọ nipa Hayatou

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹsan, oṣu kẹjọ, ọdun 1946 ni wọn bi Issa Hayatou niluu Garoua, orileede Cameroon.

Hayatou ni aarẹ ajọ to n sakoso ere bọọlu (CAF) to pẹ julọ lagbaye.

Ọdun 1988 ni wọn yan an sipo aarẹ CAF, to si gbe ijọba silẹ lọdun 2017.

Hayatou wa lọmọ ọdun mejidinlọgbọn lọdun 1974, nigba ti wọn yan an gẹgẹ bi akọwe agba fun ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lorileede Cameroon.

Bakan naa ni wọn tun yan an gẹgẹ bi alaga FA lọdun 1986. Ọdun naa ni wọn yan an gẹgẹ bi ọmọ igbimọ iṣakoso CAF.

Lẹyin ti aarẹ CAF nigba naa, Ydnekatchew Tessema to jẹ ọmọ orileede Ethiopia fẹyinti ninu oṣu kẹjọ, ọdun 1987, wọn dibo yan Hayatou gẹgẹ bi aarẹ karun-un fun ajọ naa.

Wọn yan Hayatou gẹgẹ bi aarẹ fidihẹ fun ajọ FIFA lọdun 2015 to ṣiṣẹ takuntakun titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2016 to gbe ijọba silẹ fun Gianni Infantino to n ṣakoso lọwọ.

Hayatou dije lati du ipo aarẹ FIFA, ṣugbọn to padanu sọwọ Blatter, ẹni ti wọn le danu lọdun 2016, ko to di pe oun di aarẹ fidihẹ.

Ọmọ igbimọ pataki fun ajọ to n ṣakoso idijẹ Olympic lagbaye (IOC) ni Hayatou jẹ ko to ku.

Lọdun 2010, ileeṣẹ BBC fi ẹsun gbigba owo ẹyin kan Hayatou lọdun 1990s nipa gbigbe iwe aṣẹ idije ife ẹyẹ agbaye fun ileeṣẹ amohunmaworan.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2017, ọmọ ilẹ Malagasy ni, Ahmad Ahmad fopin si iṣakoso Hayatou gẹgẹ bi arẹ CAF, nigba to bori ninu eto idibo.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un, ọdun 2017 ni Aarẹ Paul Biya ti orileede Cameroon yan Hayatou gẹgẹ bi aarẹ ile-ẹkọ to n ṣakoso ere bọọlu lorileede naa.

Wakati diẹ lo ku ki Hayatou pe ẹni ọdun mejidinlọgọrin ko to di pe ọlọjọ de.