Ìjọba Brazil kéde ìbánikẹ́dùn ọlọ́jọ́ mẹ́ta fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú

Aworan ibi iṣẹlẹ ijamba naa

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orilẹede Brazil, Luiz Inácio Lula da Silva ti kede ọjọ mẹta lati ṣe ọfọ jakejado orilẹede naa fun awọn eeyan mọkanlelọgọta atawọn oṣiṣẹ baluu to ja lọjọ Ẹti lagbegbe São Paulo

Loju opo ayelujara X rẹ ni aarẹ orilẹede Brazil ti ṣe ikede naa lọjọ Abamẹta.

“Ni iranti awọn eeyan mọkanlelọgọta to ku ninu ijamba to waye ni Vinhedo, a ti kede ọjọ mẹta lati ṣe ọfọ wọn lorilẹede yii.”

Aworan atẹjade aarẹ orilẹede Brazil

Oríṣun àwòrán, screenshot

Gbogbo awọn eeyan to wa ninu ọkọ baluu Voepass flight to ja ni ipinlẹ São Paulo lorilẹede Brazil naa lo ku gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ilu Valinhos, nitosi ilu Vinhedo nibi ti baluu na ti ja ṣe sọ.

Wọn ni awọn ero mẹtadinlọgọta ati oṣiṣẹ baluu mẹrin lo wa ninu baluu naa nigba to ja lọjọ Ẹti.

Awọn alaṣẹ sọ pe ori ile kan ti awọn eeyan n gbe ni baluu naa ja si.

Awọn alaṣẹ ni ilu Vinhedo ni ipinlẹ São Paulo nibi ti baluu naa ti ja sọ pe, ile kan ṣoṣo lo bajẹ, bẹẹ ni ko si eeyan kankan to farapa lasiko ijamba naa.

Ileeṣẹ amohunmaworan ilẹ Brazil nni, GloboNews ṣafihan aworan agbegbe nla kan ti ina eefin ti n ruyọ soke nibi ti ile pọ si.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn ọlọpaa ati awọn oṣiṣẹ panapana ti sare debẹ, koda, loju ẹsẹ ni wọn ti ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ ile iwosan to wa nitosi.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ Flightradar24 ṣe sọ ninu iwadii wọn, ọdun 2010 ni wọn ṣe ọkọ baluu ọhun, to si gbera kuro ni Cascavel ni deedee agogo mejila ku iṣẹju mẹrin ọsan (14:56 GMT).

Wakati kan aabọ lẹyin rẹ ni wọn tun pada gburo ọkọ baluu naa.

Aarẹ Brazil, Luiz Inácio Lula da Silva, ti lọ ṣe isinmi iṣẹju kan nibi ijamba ọhun, ibẹ si lo ti sọrọ.

O gbe iroyin iṣẹlẹ ijamba naa soju opo ayelujara rẹ: “O ba ni lọkan jẹ gidi. Gbogbo iwa iṣọkan ati akikanju mi lọ sọdọ gbogbo mọlẹbi ati awọn ọrẹ awọn to padanu ẹmi wọn yii.”

A gbọ pe ikọ panapana meje ọtọọtọ ni wọn sare debi iṣẹlẹ naa ni pajawiri lati ṣiṣẹ wọn.

Awọn alakoso ileeṣẹ panapana ni São Paulo gbe soju opo ‘X’ wọn pe “Ijamba ọkọ ofurufu, ikọ meje lo wa nibẹ, eyi ni iroyin to wa nilẹ.”

Siwaju sii ni awọn alakoso sọ pe ilu to sunmọ Valinhos ti ran awọn oṣiṣẹ ogun lọ sibi iṣẹlẹ ọhun ni Vinhedo.

Ileeṣẹ to n ṣe ọkọ baluu ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣe iranwọ fun iṣẹ iwadii

Awọn ileeṣẹ to ṣe ọkọ baluu to ja lulẹ yii, ATR ti gbe atẹjade sita lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ileeṣẹ ilẹ Faranse ati Italo (Franco-Italian) naa sọ pe wọn ti fi to wọn leti lori ohun toṣẹlẹ ni Vinhedo, Brazil, eyi to nii ṣe pẹlu ọkan lara awọn ọkọ baluu, ATR 72-500.

“Erongba wa wa pẹlu gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ yii,” wọn sọ ninu atẹjade naa.

Wọn fi kun ọrọ wọn pe awọn akọṣẹmọṣẹ ATR wa nikalẹ lati ran iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ nipa ohun to ṣokunfa ijamba naa ati awọn onibara wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ọkọ̀ òfúrufú tó kó èèyàn 62 já lulẹ̀ ní Brazil

Brazil plane crash

Oríṣun àwòrán, Alamy

Ọkọ ofurufu kan to ko eeyan mejilelọgọta ti ja lulẹ ni Brazil, ti gbogbo ero inu rẹ si jade laye.

Agbegbe São Paulo ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ileeṣe ọkọ ofurufu Voepass sọ pe agbegbe Cascavel, nipinlẹ Parana ni ọkọ ofurufu naa ti n bọ, to si n lọ siluu São Paulo ko to ja lulẹ niluu Vinhedo.

Awọn fidio to wa lori ayelujara ṣafinhan bi ọkọ ofurufu naa ṣe jabọ lati oju ofurufu to si gbina lẹyin to balẹ tan.

Ero mejidnlọgọta ni ọkọ ofurufu naa ko, toun ti oṣiṣẹ inu rẹ ti wọn jẹ mẹrin.

Awọn alaṣẹ agbegbe ti ọkọ naa ja si ti sọ pe ko si ẹnikẹni ninu awọn ero ọkọ ọhun to moribọ.

Wọn sọ siwaju si pe ile ti awọn eeyan n gbe ni ọkọ ofurufu naa ja le lori.

Ileeṣẹ amohunmaworan GloboNews ni Brazil ṣafihan ibi ti ọkọ naa ja si ti ọpọlọpọ eefin si n jade nibẹ.

Awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ panapana ti wa nibẹ, wọ si ti ke si awọn ileeṣẹ iwosan to wa nitosi ki wọn maa n murasilẹ lati gbalejo.

Aarẹ Luiz Inácio Lula da Silva ti ba gbogbo awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ kẹdun.

Aarẹ sọ loju opo ayelujara rẹ pe iṣẹlẹ naa “jẹ eyii to buru jai, mo ba awọn ẹbi atawọn ọrẹ awọn to jade laye kẹdun.”