Ọkọ̀ òfúrufú já lulẹ̀ ní Nepal, èèyàn méjìndínlógún jáde láyé

Nepal plane crash

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O kere tan, eeyan mejidinlogun lo ti jade laye lẹyin ti ọkọ ofurufu kan ja lulẹ lorilẹede Nepal.

Iroyin ni ṣe ni ọkọ ofurufu naa gbina lasiko to n gbera fun irinajo lati Kathmandu, to jẹ olu ilu orilẹede ọhun.

Ninu eeyan mọkandinlogun to wa ninu ọkọ naa, awakọ rẹ nikan ni ori ko yọ, o si ti n gba itọju bayii nile iwosan.

Ọkọ ofurufu naa to jẹ ọkan lara awọn ọkọ ileeṣẹ Saurya Airlines lo n lọ siluu Pokhara to gbajumọ fun irinajo afẹ.

Lara awọn to wa ninu ọkọ ofurufu naa ni awọn oṣiṣẹ rẹ atawọn amojuẹrọ.

Awọn fidio kan lori ayelujara ṣafihan bi ina ati eefin ṣe n jade lara rẹ ki awọn panapana to sare lọ sibẹ lati pa.

Nnkan bii aago mẹfa ku iṣẹju marundinlogun ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Agbẹnusọ ileeṣe ọlọpaa Nepal, Dan Bahadur Karki lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC.

Ẹnikan to jẹ oṣiṣẹ papakọ ofurufu ti ọkọ ọhun ti gbera sọ pe oun n gbọ nnkan to n dun bii ẹrọ ninu ọkọ naa lasiko ti wọn ṣina si.

Ileeṣẹ to ni ọkọ ọhun, Surayu Airlines maa n rinrinajo si agbegbe marun un ọtọtọ ninu Nepal, o si ni ọkọ ofurufu Bombardier CRJ-200 jet mẹta.