Ogun láwọn tó ń pè fún ìwọ́de ń fẹ́, a ò fẹ lágbègbè wa - Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀

Àwọn olùwọ́de

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá ti parọwa sáwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà gbé ẹ̀hónú gba ọ̀nà mìíràn dípò bí wọ́n ṣe ń gbèrò láti ṣe ìwọ́de tako ìjọba tó wà lódé.

Láti bí ọjọ́ mélòó kan ni ìròyìn ti gba orí ayélujára, táwọn ọ̀dọ́ kan sì ń pe ara wọn jọ láti kópa nínú ìwọ́de tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní “ìlú ò fararọ” láti fi ẹ̀hónú wọn hàn sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹjọ ọdún 2024 ni ìrètí wà pé ìwọ́de náà máa bẹ̀rẹ̀ tó sì máa wáyé fún ọ̀sẹ̀ kan.

Láti ìgbà tí ìkéde náà sì ti ń wáyé ni àwọn èèkan ìlú, ẹgbẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ti ń ṣèkìlọ̀ pé kí àwọn ọ̀dọ́ má ṣe ìwọ́de náà.

Bí ìkìlọ̀ ṣe ń wáyé látọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ káàkiri ni àwọn àgbà ilẹ̀ Yorùbá náà kò dákẹ́, tí wọ́n sì ń sọ pé àwọn kò fẹ ìwọ́de kankan nílẹ̀ Yorùbá.

Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí Baale Ekotedo ti ìlú Ibadan, òlú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo, Olóyè Taye Ayorinde ní ìwọ́de ọ̀tẹ̀ ni àwọn tó ń gbèrò ìwọ́de náà fẹ́ ṣe.

Olóyè Ayorinde ní àwọn tọ ń gbèrò ìwọ́de náà fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ da ojú ìjọba tó wà lóde délẹ̀ ni.

Àwọn olùwọ́de

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ó ní ìjọba tó wà lórí ìpò kò ì tíì lo ju ọdún kan lọ àti pé gbogbo ìpèníjà tó ń wáyé kìí ṣe ohun tó jẹ́ pé ìjọba yìí ló dá sílẹ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó sọ pé tí kìí bá ṣe wí pé ejò lọ́wọ́ nínú, kò yẹ kí àwọn èèyàn dìde ogun síjọba nítorí ogun ni ìwọ́de náà jọ ní irú àsìkò yìí.

Ó fi kun pé tí àwọn èèyàn bá fẹ́ ṣe ìwọ́de kí oníkálukú lọ sí ìpínlẹ̀ rẹ̀ àti pé àwọn kò fẹ́ ìwọ́de ní ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀.

Ó ní tí wọ́n bá ṣe ìwọ́de, àwọn ọmọ jàǹdùkú le ti ara bẹ́ẹ̀ gba ìwọ́de náà mọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí wọ́n sì máa fi da omi àláfíà ìlú rú.

Ó rọ àwọn ọ̀dọ́ láti gbájúmọ́ iṣẹ́ pàápàá iṣẹ́ àgbẹ̀ dípò lílo àsìkò láti fi ṣe ìwọ́de tí kò ní ṣe àǹfàní kankan fún ìlú.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọ Oodua ní àgbáyé ìyẹn Yoruba Council Worldwide (YCW), Oladotun Hassan sọ pé láti ìgbà tí ààrẹ Tinubu ti wà lórí ipò ló ti ń ṣe ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ láti fi mú ayé dẹrùn fún gbogbo èèyàn.

Ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan ìwúrí ni Tinubu ń ṣe bíi fífún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láṣẹ láti máa ná owó wọn fúnra wọn àti sísọ owó oṣù tó kéré jùlọ di #70,000 lẹ́nu ìgbà tó di ààrẹ àti pé kò yẹ kó jẹ́ pé wọ́n máa ṣe ìfẹ̀hónúhàn ni.

Hassan ní ó fojú hàn pé ìwọ́de tí wan fẹ́ ṣe náà ní ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú àti pé irúfẹ́ ìwọ́de tó wáyé lọ́dún 2020 ìyẹn #Endsars kò bí èso rere.

Ó ní ìdí táwọn àgbà Yorùbá ṣe ń tako ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Eko kò ṣẹ̀yìn àwọn nǹkan tó tẹ̀yìn ìwọ́de #Endsars jáde àti pé ìwọ́de tí àwọn kan ń pè fún lásìkò yìí dàbí wí pé wọ́n ń pè fún ogun ni.

Ó sọ pé Tinubu nìkan kọ́ ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa wọ́ ìdí rẹ̀, ó ní àwọn gómìnà àti ọ̀pọ̀ mínísítà ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ bá sọ̀rọ̀.

Ó fi kun pé nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Kenya náà yẹ kó jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà nítorí ìwọ́de náà padà di nǹkan tí ẹ̀mí àwọn èèyàn ń lọ sí.

Ó pàrọwà sáwọn ọ̀dọ́ láti pè fún ìjíròrò pẹ̀lú ààrẹ dípò láti máa gbèrò ìwọ́de.

Bákan náà ló rọ ààrẹ láti pèsè ààyè tí àwọn ọ̀dọ́ fi lè máa rí ààrẹ tàbí aṣojú ààrẹ bá sọ̀rọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ kóówá wọn.

Ó ní kò yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ fàyè sílẹ̀ fún àwọn olóṣèlú láti máa lò wọ́n tako ara wọn.

Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àtàwọn àgbààgbà nílẹ̀ Yorùbá fọhùn lórí ìwọ́de tó ń bọ̀

Aworan ifẹhonuhan ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati igba ti iroyin ti lu sita wi pe iwọde ati ifẹhonuhan "ilu o fara rọ" alagbara kan yoo bẹrẹ lorilẹede yii lọjọ kini oṣu kẹjọ ọdun yii, ni ọkanojọkan ariwisi ti n waye lati ẹnu oriṣiriṣi ẹgbẹ ati awọn alẹnulọrọ.

Bi awọn kan ṣe n parọwa pe ki awọn ọmọ Naijiria jawọ ninu ifẹhonuhan naa, ni awọn igun mii n fi ikilọ lede wi pe ki ẹnikẹni ma gbe iwode ati ifẹhonuhan naa de agbegbe awọn.

Lara awọn ẹgbẹ akọkọ to kilọ fun awọn oluwọde to n gbero lati ṣe ifẹhonuhan nilẹ Yoruba ni ẹgbẹ kan to n risi igbayegbadun ilẹ Yoruba ti wọn pe ni "Yoruba Welfare Group, YWG".

Ninu atẹjade kan ti wọn fi ranṣe si awọn oniroyin lorukọ aarẹ ẹgbẹ naa, Comrade AbdulHakeem Adegoke, YWG kede wi pe gbogbo ilẹ Yoruba, bẹrẹ lati ipinlẹ Eko, Ọyọ, Ogun, Ọṣun, Ondo titi to fi de ipinlẹ Ekiti ti di eewọ fun ẹnikẹni to n gbero lati ṣe iwọde tako aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ati ijọba Naijiria ninu oṣu kẹjọ ọdun yii.

'Ko si ọmọ ọkọ ilẹ Yoruba ti yoo kopa ninu iwọde'

Ẹgbẹ naa fi idaniloju han wi pe ko si ọmọ ọkọ ilẹ Yoruba kan ti yoo kopa ninu iwọde naa, gẹgẹ bi o ṣe n ke si gbogbo awọn adari ẹya mii to n gbe nilẹ Yoruba lati t'ọwọ ọmọ wọn bọṣọ nitori gbogbo igbiyanju ati ṣe akoba fun ẹmi tabi dukiya awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni ẹgbẹ naa yoo tako.

Ẹgbẹ awọn ọdọ ilẹ Yoruba kan ti wọn pe ni "The Yoruba Youth Socio-cultural Association (YYSA)" naa ti jẹjẹẹ lati daabo bo ilẹ baba wọn lọwọ awọn oluwọde to n gbero lati fọn si igboro bẹrẹ lati ọjọ kini oṣu kẹjọ.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa buwọlu niluu Ibadan lorukọ aarẹ wọn, Olalekan Hammed ati akọwe ẹgbẹ, Olawale Ajao, wọn ni ẹgbẹ naa ti ṣe awari erongba awọn janduku kan to fẹ fi ẹmi ati dukiya awọn eeyan ṣofo nipa didarapọ mọ iwọde naa.

Ẹgbẹ YYSA fi ikilọ lede wi pe ki gbogbo ẹni to n gbero lati fi iwọde naa ṣe ibi tun ero wọn pa.

"Gbogbo ẹya to ba kopa ninu iwọde tako ijọba Naijiria lo maa n ri idarijin gba lẹyinọrẹyin, yatọ si ẹya Igbo"

Yatọ si awọn ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba to kọkọ fi ikilọ lede lori iwọde to n bọ lọna, agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ẹyw Igbo lorilẹede Naijiria, "Ohanaeze Ndigbo" naa ti ke si gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn lati kọ eti ọgbọin si iwọde to n bọ lọna.

Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Alex Ogbonnia fi ranṣẹ si gbogbo ọmọ ẹgbẹ lọjọ Aje,

aarẹ ẹgbẹ naa lagbaye, Dr. Emmanuel Iwuanyanwu ṣe alaye wi pe gbogbo ẹya to ba kopa ninu iwọde tako ijọba Naijiria lo maa n ri idarijin gba lẹyinọrẹyin, yatọ si ẹya Igbo. Fun apẹrẹ, o ni atimọle ti Mazi Nnamdi Kanu wa titi di oni ti fa ọpọlọpọ idaamu fun ẹya Igbo.

Ẹgbẹ naa ni ọpọlọpọ ipenija ni ẹya naa ti ni loriẹede yii, ṣugbọn wọn kawọ gbera lai ja nitori pe "Igba to le koko kii pe, awọn eeyan to ba le koko nikan ni wọn maa n pẹ".

Bakan naa ni ọmọ ṣe ṣe ori ni agbegbe Ariwa orilẹede yii, nitori ikilọ ti jade nibẹ naa pe ẹnikẹni ko gbudọ kopa ninu iwọde to n bọ lọna.

Ẹgbẹ ẹya ariwa kan ti wọn pe ni The Northern Ethnic Youth Group Assembly (NEYGA)" ti pinnu lati yọwọ ninu iwọde ti yoo bẹrẹ lọjọ kini oṣu kẹjọ ọdun yii.

Ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ awọn oniroyin, ẹgbẹ naa ke si awọn ọdọ orilẹede Naijiria ati awọn akẹkọọ lati ṣe atilẹyin fun aarẹ Bọla Tinubu, pẹlu alaye wi pe gbogbo ipenija to n ba Naijiria finra lọwọlọwọ bayii ni Tinubu jogunba lati ọwọ aarẹ ana, Muhammadu Buhari.

Ẹgbẹ naa ṣe alaye pe iwọde ati ifẹhonuhan lasiko yii le ṣe akoba fun iṣokan orilẹede Naijiria.

Agbẹnusọ NEYGA, Ibrahim Dan-Musa ke si awọn ọmọ Naijiria lati fun Tinubu ni aaye lati mu awọn ileri rẹ ṣẹ nitori awọn atunto ti o n ṣe ti n so eso rere.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa rawọ ẹbẹ si awọn to n gbero iwọde tako ijọba

Kọmisana Ọlọpaa to n ṣe akoso ilu Abuja, Benneth Igweh ti rawọ ẹbẹ si awọn olugbe ilu naa lati yago fun iwọde ti yoo waye jakejado orilẹeede yii latile dena adanu awọn ohun elo amayedẹrun ti ijọba ṣe si ilu naa.

Igwe pa arọwa naa saaju iwọde to n bọ lọna lasiko to n ṣe afihan awọn ọdaran to ṣekupa Ọgagun Uwen Harold Udokwerre niluu Abuja lọjọ kejilelogun ọṣu kẹfa ọdun yii.

O ni ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ni awọn ti padanu sẹyin ninu igbiyanju lati dẹkun iwa ọdaran, adanu mii ko si tun gbudọ waye nipasẹ iwọde ti awọn ọmọ Naijiria n gbero.

Ọna ti ijọba le gbe lati dena iwọde to n bọ- Egbẹ oṣiṣẹ NLC

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, "Nigeria Labour Congress, NLC," Joe Ajaero ti rọ aarẹ Bọla Tinubu lati sọ asọyepọ pẹlu awọn adari ikọ to n gbero lati ṣe iwọde nitori inira to n koju awọn ọmọ orilẹede yii.

Ajaero ni gbogbo eeyan lo lẹtọọ lati fi ẹhonuhan, ọpọlọpọ ọmọ orilẹede Naijiria si ni inu n bi nitori ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Ninu atẹjade ti o to awọn oniroyin lọwọ, Ajaero tọka si awọn abajade iṣẹ iwadii lori ipo ti ọrọ aje orilẹede yii de duro. O ni pupọ idile lo n lakaka lati jẹun, ti ẹgbẹlẹgbẹ si n munkun ninu oṣi ati iṣẹ.

O ni nnkan iwọsi gbaa ni bi ijọba ṣe n sọ wi pe iwọde naa ni ọwọ oṣelu ninu.

Aarẹ NLC tẹsiwaju pe awọn eeyan ilu nilo ki ijọba tẹti si wọn, ki ijọba si tun fi ọkan ikaanu han.

O kilọ fun ijọba apapọ wi pe fifi ọwọ lile mu awọn kọ ni ọna abayọ si irora ati awọn ipenija wọn.

Ijọba apapọ kesi awọn to n gbero lati wọde pe ki wọn yi ero wọn pada

Aarẹ Bọla Tinubu ti ke si awọn ọmọ Naijiria lati jawọ ninu iwọde ti wọn n gbero, pẹlu alaye wi pe gbogbo ipa ni ijọba sa lati yanju inira to n ba wọn finra.

Ninu ọrọ ti o sọ lọjọ Aje lasiko ti akọwe ijọba apapọ, George Akume ṣoju fun un nibi akanṣe ipade ti o ṣe pẹlu agbarijọpọ awọn lọbalọba orilẹede yii niluu Abuja, aarẹ Tinubu tẹpẹlẹ mọ pataki suuru ati atilẹyin awọn eeyan ilu lasiko ti nnkan le koko yii.

Tinubu bẹnu atẹ lu awọn eeyan to fẹ lo anfani ipenija to n koju orilẹede yii lati bẹrẹ iwọde, dipo ki wọn ṣe suuru fun ijọba lati wa ọna abayọ.

O rọ awọn to n gbero iwọde naa lati ranti awọn igba ti iru igbesẹ bayii ti ṣe akoba fun iṣọkan orilẹede yii.

O fi awọn ilu bii India ati Sudan ṣe apẹrẹ wi pe pẹlu eeyan to le ni igba Milliọnu, ko yẹ ki orilẹede yii fi aye gba iru iyapa bẹẹ.