Ọlọ́pàá ti èèyàn 60 mọ́lé torí ìwọ́de tako ìjọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ eeyan lo ti dero atimọle niluu Kampala, to jẹ olu ilu Uganda lẹyin ti wọn kopa ninu ifẹhonuhan kan ti ijọba fofin de ṣaaju.
Awọn agbẹro sọ fun awọn akọroyin pe nnkan bi ọgọta eeyan, to fi mọ gbajumọ atọkun redio kan atawọn ọdọ mẹta ni ijọba ti gbe lọ sile ẹjọ lori iwọde ọhun.
Ṣaaju ni Aarẹ Yoweri Museven, to ti tukọ orilẹede naa fun ogoji ọdun ti kọkọ kilọ pe awọn awọn eeyan naa n fi ina ṣere ti wọn ba le ṣe ifẹhonuhan ọhun.
Ori ẹrọ ayelujara lawọn oluwọde naa ti pinlẹ iwọde ọhun latari ẹsun lilu owo ni ponpo ti wọn fi kan awọn eekan ijọba kan.
Lara ohun to tubọ ki awọn eeyan orilẹede naa laya lati wọde ko ṣẹyin iwọde agbayanu to waye ni Kenya ṣaaju, eyii to mu ki Aarẹ Wiliam Ruto ṣe awọn atunṣe kan nipa owo ori.
Ki iwọde naa to waye, ni ileeṣẹ ọlọpaa Uganda ti ni oun ko fontẹ lu iwọde naa nitori oun ko ni gba ki ẹnikẹni da omi alaafia orilẹede naa ru.
Lọjọ Iṣẹgun lawọn ọlọpaa kogbọregbe yabo aarin igboro, ti awọn agbofinro mii si duro wamuwamu lati daabo bo ile aṣofin.
Awọn aworan lati Kampa ṣafihan awọn akọle tawọn oluwọde gbe dani, ninu eyii ti wọn kọ awọn ọrọ bii ‘ Ale fopin si iwa ajẹbanu” ti awọn mii si gbe akọle bii ‘a kii se oluwọde oni jagidijagan.”
Awọn aworan mii ṣafihan bi awọn ọlọpaa ṣe n fi ṣikun ofin mu awọn oluwọde, ti wọn si n ti wọn sinu ọkọ wọn.
Lara awọn ti ọlọpaa ti mọle ni gbajumọ atọkun orei redio, Faiza Salima atawọn mẹta to ṣahgbatẹru iwọde naa, George Victor Otieno, Kennedy Ndyamuhaki, ati Aloikin Praise Opoloje.
Olori ẹgbẹ alatako, Bobi Wine, ti sọ pe ẹgbẹ oun yo pese awọn agbẹjọro fun awọn nilo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ Iṣẹgun lawọn ọlọpaa kogbọregbe yabo aarin igboro ti awọn agbofinro mii si duro wamuwamu lati daabo bo ile aṣofin.
Awọn aworan lati Kampa ṣafihan awọn akọle tawọn oluwọde gbe dani, ninu eyii ti wọn kọ awọn ọrọ bii ‘le fopin si iwa ajẹbanu” ti awọn mii si gbe akọle bii ‘a kii oluwọde oni jagidijagan.”
Awọn aworan mii ṣafihan bi awọn ọlọpaa ṣe n fi ṣikun ofin mu awọn oluwọde, ti wọn si n ti wọn sinu ọkọ wọn.
Lara awọn ti ọlọpaa ti mọle ni gbajumọ atọkun orei redio, Faiza Salima atawọn mẹta to ṣahgbatẹru iwọde naa, George Victor Otieno, Kennedy Ndyamuhaki, ati Aloikin Praise Opoloje.
Olori ẹgbẹ alatako, Bobi Wine, ti sọ pe ẹgbẹ oun yo pese awọn agbẹjọro fun awọn nilo rẹ.
Àwọn èèyàn tó gbèrò ìfẹhonúhàn ń fi iná ṣeré- Ààrẹ ṣekìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹedde Uganda Yoweri Museveni ti ṣekilọ fun awọn olufẹhonuhan pe wọn n fi ina ṣere ti wọn ba tẹsiwaju lati se ifẹhonuhan lọ si ile igbimọ aṣofin lọjọ Isẹgun, ọjọ ketalelogun oṣu keje ọdun 2024.
Awọn ọdọ Uganda ni wọn ti gbero lati se ifẹhonuhan, ti wọn si ti n ko ara wọn jọ lori ayelujara lati pe fun fifi opin iwa ọdaran ati sise owo ilu mọkumọku to wọpọ lorilẹede naa.
Iwọde to waye lorilẹede Kenya jẹ ọkan lara idi ti ọpọ awọn ọdọ ni awọn orilẹede to sumọ fi n gba lero lati se ifẹhonuhan ti wọn lati fi bere fun ayipada lọwọ ijọba.
Ninu ọrọ rẹ lori ẹrọ momaworan, Maseveni kilọ fun awọn eeyan to wa ni idi ifẹhonuhan pe ijọba ko ni fi aye gba wọn rara.
“A n siṣẹ lori bi a se pese ọrọ... ẹyin fẹ di wa lọwọ. Ẹ n fi ina sere nitori a ko ni gba yin laye lati di wa lọwọ,” o salaye.
Museveni ni awọn alatako rẹ fẹsun kan pe o n dari orilẹede naa pẹlu ọwọ lile lati igba to gba agbara ni ọdun 1986 sugbọn awọn alatilẹyin rẹ kan sara si fun bi o ṣe jẹ ki alaafia jọba lorilẹede naa.
Aarẹ tun fẹsun kan awọn eeyan to n gbero ifẹhonuhan pe wọn sisẹ pọ pẹlu awọn ojoji lati da wahala silẹ lorilẹde Uganda sugbọn o jẹ ko di mimọ pe oun ko ni fi aye gba irufẹ iwa naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe awọn ko ni fi aye gba ki iwọde naa waye.
Ọkan lara awọn olori to gbero ifẹhonuhan naa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe awọn yoo tẹsiwaju pẹlu ifẹhonuhan naa.
“A ko nilo aṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati se iwọde alaafia. Ẹtọ wa ni,” Louze Aloikin Opolose salaye.
Ijọba UK ati US fofin de olori ilr igbimọ aṣofin Uganda, Anita Annet Among ni ibẹrẹ ọdun yii lẹyin ti wọn fẹsun sise owo mọkumọku kan.
Among ni oun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan.
Igbesẹ ijọba US ati UK ni ko fi aye gba Among lati rin irinajo lọ si awọn orilẹede naa.















