Ọmọ Nàìjíríà tó lé ní àádọ́ta táwọn kan fi ṣòwò ẹrú lọ Ghana ti móríbọ́ wálé

Aworan awọn eeyan to de lati Ghana

Oríṣun àwòrán, NAPTIP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ NAPTIP to n gbogun ti fífi eeyan ṣe owo ẹru ati kata-kara ti ko eeyan mokandinlọgọta tawọn kan fi ṣe katakara lọ si orilẹede Ghana lati ipinlẹ Kano pada wale.

Awọn ọkunrin ati obinrin to fi mọ awọn ọmọde ti wọn ko ju ọmọ ọdun mẹtadinlogun si mejidinlogun lọ wa lara awọn eeyan ti ajọ NAPTIP doola ọhun.

Koda, awọn ọmọ kekere ti wọn ko ti i ju ọdun mẹta si mẹrin lọ naa wa lara wọn.

"Mẹtadinlaadọta ninu awọn eeyan mọkandinlọgọta ti ajọ NAPTIP ko pada wale yii lo jẹ ọmọ ipinlẹ Kano"

Hajiya Amina Abdullahi Sani to jẹ kọmiṣọna ileeṣẹ ijọba to gbogun ti iṣẹ ati oṣi nipinlẹ Kano ṣalaye pe awọn eeyan kan lo tan awọn eeyan yii lọ si Ghana pẹlu ileri pe wọn yoo gbe igbe aye to rọrun nibẹ.

Kọmiṣọna ni "a gba iroyin pe mẹtadinlaadọta ninu awọn eeyan mọkandinlọgọta ti ajọ NAPTIP ko pada wale yii lo jẹ ọmọ ipinlẹ Kano.

Lẹyin ti a fidi eyi mulẹ tan ni a ko awọn to jẹ ti wa wale."

Hajia Sani ṣalaye pe eto ayẹwo ilera awọn eeyan yii n lọ lọwọ.

Kọmiṣọna fikun ọrọ rẹ pe bi wọn ti n ko awon eeyan kan lọ si orilẹede Ghana ni wọn n kawọn mii lọ si Libya ati Egypt pẹlu ileri lati sọ wọn di ọlọrọ.

O ni nigba ti wọn ba de ibẹ tan ni wọn maa n mọ pe owo ẹru ni wọn fẹ lọ fi wọn ṣe.

"Gbogbo awọn obinrin to de lati Ghana ni ko lọkọ ti yoo tọju wọn"

"Iwadii ti a ṣe fihan pe awọn obinrin to wa ninu awọn eeyan naa gba lati gunle irinajo lọ si Ghana tori wọn o ni ọkọ to le ṣe itọju wọn," Hajia Sani ṣalaye.

Kọmiṣọna wa rọ ijọba lati gbe igbimọ kan dide eyi ti yoo maa ṣawari awọn ọkunrin to ba sa kuro lọdọ ẹbi wọn lati le fita jẹ wọn.

Iṣoro fifi eeyan ṣe katakara ati owo ẹru nilẹ okeere ti n koju orilẹede Naijiria tipẹ.

Dipo ki iṣoro naa maa dinku, ni ṣe lo n peleke si.

Iwadii fihan pe ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn n fi ṣe owo ẹru ati kata-kara lọ si awọn orilẹ-ede Larubawa ati awọn orilẹede Afirika kan nibi ti ogun ti n lọ lọwọ.

Iwadii naa sọ pe nigba ti wọn ba de ibẹ tan ti ile ko ṣe pada si mọ ni wọn maa n fi ika abamọ bọnu.