Aya kan àti ọmọ mẹ́rin ni mo ní, àwọn obìnrin tí ẹ ń fi àwòrán wọn hàn, kìí ṣe aya mi, ohun tí ẹ ṣe fún mi, dùn mi - Akpabio

Akpabio ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, @Senator_Akpabio

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Sẹnetọ Godswill Akpabio ti tọrọ aforijin lọwọ akẹgbẹ rẹ to jẹ obinrin Sẹnetọ Natasha Akpoti Uduaghan.

Akpabio gbe igbesẹ lasiko ti apero ile igbimọ aṣofin waye loni, ọjọ Kẹtadinlogun oṣu keje ọdun 2024 lẹyin ọsẹ kan to ti sọrọ ti ọpọ ni o fi tabuku akẹgbẹ.

Ninu fọnran kan to lu sita lori ayelujara ni ọjọ Kọkandinlogun oṣu keje lo ti foju han pe aarẹ ile asofin agba naa ti tọrọ aforijin.

Ohun ti Aarẹ ile igbimọ aṣofin n tọrọ aforijin le lori ni ọrọ kan to sọ fun Sẹnetọ Natasha Akpoti Uduaghan, ẹni to n soju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Kogi pe, ko ma sọrọ ti ile o ba ti ni ko sọrọ nitori ile igbimọ aṣofin ki ṣe ile igbafẹ alẹ.

Ohun ti Natasha sọ ni “Aarẹ ile, a ko fẹ ki ofin yii ku, a fẹ se atunṣe diẹ si sir.”

Akpabio fesi pada pe,”Sẹnetọ Natasha, ni ile igbimọ aṣofin yii, ile ni lati fun ẹ ni ore ọfẹ ko sọrọ, ki o to le sọrọ sita.”

“Ha, ẹ ma binu, ẹ forijin mi” Akpoti Natasha fesi pada.

Lẹyin to tọrọ aforijin ni Aarẹ ile igbimọ aṣofin sọ pe “A ko si ni ile igbafẹ alẹ.”

Ọrọ yii lo bi ọpọ ọmọ Naijiria ninu lori ayelujara.

“Mo mẹnuba ile igbafẹ alẹ nitori awọn eeyan ibẹ ma n pariwo ju orin ti wọn n gbọ lọ, awọn ara ayelujara lo si ọrọ mi gbọ.”

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ aforijin rẹ, Akpabio ṣọrọ siwaju pe:

“Ko da, fun awa ti a ti wa ni ile igbimọ aṣofin fun ọdun mẹrindinlogun, a si n kọ ẹkọ si, a o si ma kọ ẹkọ lọ,”

O ni “Nigba ti mo n ba ọkan lara aṣofin sọrọ to jẹ obinrin, mo sọ fun un pe ko lee sọrọ nigba ti ile ko ba ti fun ni oreọfẹ lati sọrọ.

“Mo mẹnuba ile igbafẹ alẹ nitori awọn eeyan ibẹ ma n pariwo ju orin ti wọn n gbọ lọ, o ni awọn ara ayelujara ba gba si nnkan mi.”

O ṣalaye pe oun ko si lori ayelujara sugbọn iyawo rẹ pe lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ pe awọn eeyan n binu si, ti wọn si ti fi nọmba ibaraẹnisọrọ rẹ sita fun araalu pe ki wọn ma pe.

Akpabio ni “Iyawo mi gba ipe to le ni ẹgbẹrun mẹta, mo gbinyanju lati tan ọkan lara foonu mi ni mo ri pe wọn ti fi nọmba mi si ta, koda foonu ọhun pana lẹyin wakati mẹta nigba ti ipe naa pọ.

“Inu mi dun pe awọn araalu nifẹ si nnkan ti a n se nibi nitori a wa nibi fun awọn eeyan wa ni.

“Lati mọ nipa nnkan yii sẹlẹ, o tumọ si pe a sun mọ awọn araalu.” Akpabio ṣalaye.

“Wọn ṣafihan awọn obinrin kan lori ayelujara pe iyawo mi ni wọn, o si dabi pe mo ni iyawo pupọ amọ iyawo kan ni mo ni"

Gomina ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ naa ṣalaye pe ọpọ awọn araalu ni ko ni oye nipa ohun ti oun sọ sita.

O ni wọn kọ lati ri pe oun gbinyanju lati mu ariwo dinku nile igbimọ aṣofin lasiko ti ijoko n lọ lọwọ sugbọn wọn ka si nnkan mi.

“Wọn wọ ọrọ lọ ibo miiran. N ko fẹ sọ nnkan ti wọn ṣe fun mi, nitori ko yẹ ko jẹ emi ni wọn ma se fun.

“Wọn ṣafihan awọn obinrin kan pe iyawo mi wọn lori ayelujara, o wa da bi pe aarẹ ile igbimọ aṣofin ni iyawo pupọ, to si jẹ pe iyawo kan ni mo ni, to si tẹ mi lọrun.

“N ko ni tabuku si obinrin kankan. Mo ni iyawo ati ọmọ obinrin mẹrin, ti mo si n gba ladura pe ki Ọlọrun gbe ori awọn obinrin soke lọ si ipo nla lorilẹede Naijiria.

“Sẹnetọ Natasha Akpoti, mo tọrọ aforijin, to ba jẹ pe mo ti sẹ. Ti mo ba sọ pe ko maa pariwo bii igba ti a wa ninu ọja, wọn maa tun ni mo pe ẹ ni iya ọlọja.

Bi awọn eeyan wa se mu ọrọ yii fihan pe ọta pọ ninu oṣelu , ti emi naa si ni ọta nitori gbogbo wa ni a n ba awọn eeyan dupo."

Wo igba mii ti wahala bẹ lori ayelujara tori ọrọ ti aarẹ ile asofin sọ

Ki ṣe igba akọkọ ree ti Aarẹ ile igbimọ aṣofin yoo sọr,ọ ti yoo da wahala silẹ lori ayelujara.

Ni bi oṣu diẹ sẹyin lasiko eto isinku ọga agba funile ifowopamọ Access Bank, Herbert Wigwe , Aarẹ ile igbimọ aṣofin sọ awọn ọrọ kan nipa Gomina ipinlẹ Rivers.

Wahala bẹ silẹ lori ayelujara, ti ọpọ si n na ika abuku si Aarẹ ile igbimọ aṣofin fun ọrọ to sọ sita.