Wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí o ṣe le tẹ ojúlówó èsì ìdánwò JAMB rẹ jáde

Atẹjade JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n ri si idanwo aṣewọle si fasiti ni Naijiria, JAMB, ti kede pe awọn akẹkọọ to ṣe idanwo naa lọdun yii le lọ maa tẹ ojulowo esi idanwo wọn jade.

Agbẹnusọ JAMB, Ọjọgbọn Fabian Benjamin lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to ti sọ pe esi naa yoo ni aworan akẹkọọ atawọn nnkan mii ti yoo fi han pe lootọ akẹkọọ naa lo ni esi ọhun ninu.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn akẹkọọ ko ni le tẹ esi naa jade nibi to ba wu wọn ayafi awọn gbọgan CBT ti JAMB fontẹ lu nikan.

O ni awọn gbe igbesẹ naa ki awọn akẹkọọ ọhun ma baa ko sọwọ awọn onijibiti.

Ki ni pataki atẹjade esi idanwo yii?

Atẹjade esi idanwo JAMB yii ṣe pataki nitori oun ni awọn ile ẹkọ giga yoo bere fun ayẹwo lasiko idanwo ‘Post UTME.’

Esi naa ni aworan akẹkọọ, to fi mọ awọn ohun idabobo miran ti yoo mu ko ṣoro fun akẹkọọ kankan lati lo ayederu rẹ tabi lo ti akẹkọọ miran.

Atẹjade esi idanwo naa tun wulo gẹgẹ bii ẹri fun oniruru awọn iforukọsilẹ lẹyin ti akẹkọọ naa ba wọ ile ẹkọ giga tan.

JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB

Awọn ipele ti o gbọdọ tẹle lati tẹ ojulowo esi idanwo JAMB rẹ

  • Igbesẹ akọkọ ni ki o lọ si ojuko CBT ti JAMB fọwọ si
  • Wọle si oju opo naa pẹlu nọmba iforukọsilẹ JAMB rẹ
  • Lọ si ipele “Slip Printing Section” ki o si tẹ “Print Result Slip”
  • Lẹyin naa ni o maa san owo ti iye rẹ jẹ ₦1,500
  • Ti o ba ti san owo naa ni o maa lanfani lati tẹ ojulowo esi idanwo naa jade