Èèyàn 229 ló ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ yíyọ̀ tó wáyé ní Ethiopia lọ

Awọn eeyan to n daro nipa isẹlẹ ilẹ riri

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń dóòlà ẹ̀mí ní orílẹ̀ èdè Ethiopia ti ní kò dín ní òkú èèyàn 229 tí wọ́n ti yọ lábẹ́ ilẹ̀ yíyọ̀ tó wáyé ní Ethiopia.

Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà ló ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún BBC.

Àwọn aláṣẹ ni iṣẹ́ ṣì ń tẹ̀síwájú láti yọ àwọn tó há sábẹ́ ilẹ̀ àmọ́ ó ṣeéṣe kí iye àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn tún lékún si.

Adarí ẹ̀ka tó ń mójútó ìjàmbá ní Gofa, Markos Melese ní òkú èèyàn 229 ni àwọn ti yọ báyìí.

Bákan náà ni adarí ẹkún Goza, Dagmawi Ayele sọ fún BBC pé ọmọdé àti àgbà ló bá ìjàmbá náà lọ àti pé èèyàn mẹ́wàá tí wọ́n rí yọ láàyè ti wà ní ilé ìwòsàn tí wan ti ń gba ìtọ́jú.

Ethiopia landslides

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, aadọta eeyan lo ti jade laye lẹyin iṣẹlẹ ilẹ yiyọ to waye ni Ethiopia.

Iroyin ni alẹ ọjọ Aiku ati aarọ ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ojo arọrọda kan lagbegbe Gofa ti ọpọ oke wa.

Awọn alaṣe sọ pe ko rọrun lati lọ doola awọn to ha sibẹ amọ o ṣeesẹ ki iye awọn ti yoo ku pọ ju iye ti awọn kede lọ.

"Awọn araalu atawọn ọlọpaa to n gbiyanju lati yọ awọn eeyan to ha sabẹ ilẹ, ni ilẹ yiyọ tun bo mọlẹ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn aworan kan ṣafihan bi awọn eeyan ṣe korajọ sibi iṣelẹ naa ti waye ti awọn kan si n gbẹ ilẹ lati yọ awọn eeyan ti ilẹ bo mọlẹ.

Adari agbegbe Gosa, Meskir Mitku sọ pe awọn obinrin, ọmọde atawọn ọlọpaa wa lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Aṣoju ijọba kan lagbegbe ila oorun Ethiopia, Kassahun Abayneh sọ pe “ojo nla kan rọ lalẹ ọjọ Aiku, awọn eeyan kan si ku lẹyin ti ilẹ yọ.

“Laarọ ọjọ Aje, awọn araalu atawọn ọlọpaa korajọ lati yọ awọn ti ilẹ bo mọlẹ, asiko naa ni ilẹ tun yọ, to si bo awọn naa mọlẹ ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ti awọn naa si ku.”

Iha ila oorun Ethiopia ni Gofa wa, o si jẹ nnkan bii kilomita 320 si ilu Addis Ababa to jẹ olu ilu orilẹede naa.

Ila oorun Ethiopia wa lara awọn agbegbe ti ojo ti maa n pọ ju, aipẹ yii si ni iṣẹlẹ omiyalẹ bẹrẹ si n le kenka nibẹ.

Amọ ṣa, ki ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ iṣẹlẹ yii yoo waye ni Gofa.

Lọdun 2016, iṣelẹ ilẹ yiyọ mu ẹmi aadọta eeyan lọ lẹyin ti ojo rọ kaakiri orilẹede naa fun ọpọ ọjọ.

Oniruru nnkan lo n fa ojo arọrọda ọhun amọ awọn onimọ ti sọ pe ayipada oju ọjọ lo tubọ n kin iṣẹlẹ naa lẹyin.