Gọngọ sọ níbi àjọ̀dún Àdìrẹ nílẹ̀ Austria, òyìnbó ń lu ìlù, àwọn Yorùbá mújó jó
Ọjọ nla ni ọjọ ti ajọdun Adirẹ waye nilu Vienaa ni orilẹede Austria.
Ẹni ti ko le rin, ni ki wọn gbe oun nitori bi okiki ajọdun naa se gbalẹ to.
Ọdun kẹwa ree ti wọn yoo se ajọdun naa, eyi ti awọn eekan ilu nilẹ Naijiria ati ni Austria peju si.
Lara awọn eekanlu to bawọn kopa nibi ajọdun naa ni Ọlọta tilu Ọta, Ọba Adeyemi Obalanlege.
Bakan naa ni asoju ilẹ Naijiria nilẹ Vienna, Haliru Bello ko gbẹyin nibẹ.
Oludari ibudo ti wọn n ko ohun isẹmbaye si nilu Vienna, Jonathan Finn naa bawọn peju sibi ayẹyẹ alarinrin naa.

Ajọdun Adirẹ ti kuro ni ti ẹya Yoruba nikan, awọn ẹya Hausa, Igbo naa n gbe larugẹ - Ọlọta
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa ajọdun Adirẹ naa, Ọlọta tilu Ọta, ba Adeyemi Obalanlege salaye pe ajọdun naa ti gbajumọ yika agbaye.
"Ọdun kẹwa ti wọn ti n se ajọdun naa lorilẹede Vienna ree, o si ti kuro ni ajọdun awa ẹya Yoruba nikan.
Awọn ẹya Hausa, Igbo ati awọn eeyan ilẹ Austria lo n gbe ajọdun naa larugẹ bayii.
Lootọ, ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni wọn ti n se asọ Adire amọ o ti di gbajumọ yika agabaye.
Mo wa n gbosuba fun gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun, fun atilẹyin rẹ lori agbelarugẹ ajọdun Adire naa.

Ajọdun Adirẹ lo n se afihan asa Naijiria lapapọ, kii se ti Yoruba nikan - Asoju Naijiria ni Austria
Ninu ọrọ tiẹ naa fun BBC Yoruba, asoju ilẹ Naijiria lorilẹede Austria, Ambassador Haliru Bello salaye pe ajọdun Adirẹ naa ti gbajugbaja yika orilẹede naa.
"Ajọdun asa ilẹ Yoruba ti wọn n se nilẹ Austria yii ti gbajumọ kọja ilẹ Naijiria nikan.
Ajọdun naa si lo n fun ilẹ Naijiria ni anfaani lati se afihan asa ajogunba ilẹ wa.
O tun fun wa lanfaani lati safihan awọn ẹbun ti Ọlọrun fawọn ọmọ Naijiria, ounjẹ wa, awọn orin wa to fi mọ asọ wiwọ wa.
Eleyi lo jẹ ki awọn eeyan ti kii se ara ẹya wa kọ lati maa bọwọ nla fun asa wa.
Ajọdun Adirẹ yii ko wa fawọn ọmọbibi Yoruba nikan amọ o fun gbogbo ẹya to wa nilẹ Austria ni anfaani lati parapọ ni ọkan bii ọmọ orilẹede Naijiria."

Ajọdun Adirẹ jẹ ọkan lara ajọdun patati ti a n se nilẹ Austria - Oludari ibudo nnkan isẹmbaye
Bakan naa, Oludari ibudo ti wọn n se nnkan isẹmbaye lọjọ si nilẹ Austria, Jonathan Fynn ba BBC Yoruba sọrọ.
Fynn fidi rẹ mulẹ pe ọdun kẹwa ree ti ajọdun Adirẹ ti n waye lorilẹede naa, eyi ti ọpọ eeyan maa n fi oju sọna fun.
"Ajọdun Adirẹ jẹ ara ajọdun pataki ti a maa n se lorilẹede Austria ni ọdun kan.
Mo ti wa si orilẹede Naijiria ni ọpọ igba nitori isẹ mi ni nnkan se pẹlu agbelarugẹ asa ati awọn ibudo ise nnkan isẹmbaye lọjọ si to wa ni ilẹ Naijiria."







