UNESCO gbóṣùbà káre fún àyẹyẹ ọdún Sango, kedé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àyẹyẹ àjogúnbá

Aworan ayẹyẹ ọdun Sango

Oríṣun àwòrán, UNESCO/X

Igbimọ to n ṣe igbelarugẹ ẹkọ, imọ sayẹnsi ati aṣa lagbaaye UNESCO ti kan saara si ayẹyẹ ọdun Sango to maa n waye ni ilu Oyo.

Igbimọ yi gboṣuba kare fun ayẹyẹ naa ti o si ka papọ mọ awọn ayẹyẹ ajogunba.

Ikede yi waye lẹyin ijoko igbimọ to n ṣe idaabo bo ohun ajogunba ti wọn ṣe ni Cresta Mowana Resort to wa ni Kasane lorileede Botswana.

Nibi ijoko yii, wọn kede awọn ohun adayeba tuntun ti wọn fi kun awọn eleyi to wa nilẹ yala nipa iṣẹ ọna, ajọdun tabi imọ adayeba tawọn eeyan fi n ṣe anfaani lawujọ.

Labẹ isọri yi ni wọn ti kede ayẹyẹ ọdun Sango to jẹ ọdun pataki nilẹ Yoruba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki lo rọ mọ ọdun Sango fawọn eeyan ilu Oyo?

Aworan awọn ọmọlẹyin Sango nibi ajọdun Sango nilu Oyo

Nilẹ Yoruba, ayẹyẹ ọdun Sango ni wọn maa fi n ṣe idanimọ ibẹrẹ ọdun tuntun.

O jẹ ajọdun iṣẹnbaye to maa n waye ni Sango ni aafin Koso.

Ajọdun ọlọjọ mẹwaa yii ni ohun ṣe pẹlu aṣa,isẹṣe ati ẹsin awọn Yoruba nilu Oyo.

Ni iranti Tella Oko, Alaafin kẹta Oyo ti wọn gbagbọ pe o jẹ atunwa Sango ni wọn fi n ṣe ajọdun yi bakan naa.

Nigba ti wọn ba bẹrẹ ajọdun yi loṣu Kẹjọ awọn ẹlẹsin Sango a maa pin iṣu sisun ti wọn a si maa fi epo pupa jẹ.

Ati ọkunrin ati obinrin lo maa n diri wọn ti wọn a si wọ aṣọ pupa pẹlu ilẹkẹ lọrun wọn.

Tilu tifọn ni wọn fi n ṣe ajọdun yi ti o si jẹ anfaani fawọn eeyan ni paapa awọn ọmọde lati mọ nipa aṣa ati iṣẹṣẹ babanla wọn.

Ki eeyan to le mọ nipa agbara Sango ati ko to le ni iru agabara naa, eeyan yoo kopa ninu idanilẹkọ gẹgẹ bi ọmọlẹhin Sango.

Ọna ti mu irẹpọ wa laarin awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni ayẹyẹ ajọdun Sango yi jẹ.

Jakejado Naijiria ati lẹyin odi si ni awọn eeyan ti wa n ba wọn kopa ninu ajọdun yi top maa n waye loṣu Kẹjọ ọdọọdun.