Ayẹyẹ ọdún Sango lẹ̀yìn ìpapòdà Alaafin Lamidi Adeyemi III wáyé, ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ rèé

SANGO FESTIVAL 2022

Ayẹyẹ aṣekagba ayajọ ọdun Sango agbaye lo waye ninu gbagede aafin kabiyesi iku babayeye Ọba Lamidi Adeyemi III.

Ayẹyẹ ọhun ni ko kun fun eroworan bi ti atijọ

Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, eyii ko ṣẹyin iku Alaafin ti olu Oyo to gbese ni kopẹkopẹ yii.

SANGO FESTIVAL 2022

Ọpọlọpọ ẹgbẹ oṣere lati ipinlẹ Oyo, Kwara ati ilu Oyo lo jade lati da awọn oluworan laraya.

Aṣoju ijọba ipinlẹ Oyo, Ademola Ige, alaga ijọba ibile Atiba Mojisola Adeojo lo wa ni ibi ayẹyẹ Sango agbaye ọdun yii.

Ninu ọrọ ti awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Oyo sọ,wọn pe fun irẹpọ ati igbagbe àlàáfíà laarin gbogbo ṣsin to wa ni ipinlẹ oyo.

Eto ayẹyẹ Sango agbaye ni o jẹ akọkọ iru rẹ lẹyin iku kabiyesi Oba Lamidi Adeyemi III.