Àwọn tó sọ pé kò sí owó ní Nàìjíríà àfi ká yáwó ń pa irọ́ fáráàlú ni – Kwankwaso

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People Party, Sẹnetọ Rabiu Musa Kwankwaso ti ni ko si otitọ ninu ọrọ kan ti awọn oloṣelu ma sọ pe ko si owo lorilẹede Naijiria, afi ki awọn lo yawo fi ṣe isẹ akanṣe faraalu, lo jẹ irọ ati itenijẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News, Gomina ana ipinlẹ Kano ni ki awọn oloṣelu dẹkun lati ma pa irọ faraalu pe ko si owo ninu apo ijọba.
Kwankawso ni ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria ba gba oun laye lẹyin ti oun ti fi apẹẹrẹ rere silẹ nipinlẹ Kano, Naijiria yoo ri iyatọ.
O tẹsiweaju pe nigba ti oun kọkọ jẹ gomina ipinlẹ Kano lọdun 1999, oun ba awọn ọpọlọpọ owo ti ijọba to kogba wọle jẹ, sungbọn oun ripe oun san awọn owo naa ki oun to fi ijọba sile, koda oun ko fi gbese sile nigba ti oun gbe ijọba silẹ.
Kwankawao ni ọpọlọpọ awọn oloselu ni ko fẹran lati ma sọ otito ti wọn ba bọ si oṣelu.
O ni oun ko le sọ boya ijọba to wa lode lorilẹede Naijria n ṣe oun ti araalu fẹ sugbọn gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria mọ bi nkan ṣe n lọ pẹlu ọrọ abo.
“Bi wọn sẹkupa eniyan ni awọn eeyan sa kuro ni ile wọn ati ilu awọn.
“Mo rọ ijọba orilẹede Naijiria lati tete wa ojutu si gbogbo rogbodiyan yii ki alaafia le de ba awọn olugbe orilẹede yii.
“isẹ n ba ọpọlọpọ finra lorilẹede Naijiria.”












