Ìdí tí a fi lè fi owó kún owó oṣù òṣìṣẹ́ rèé - Ààrẹ Buhari

aworan Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ idi ti ijọba apapọ ko le fi owo kun owo oṣu awọn osisẹ gẹgẹ bi o ṣe hu wọn lati ṣe.

Aarẹ Buhari ni bi ikọlu, ipenija arun korona ati bi rogbodiyan ṣe n waye lorilẹede Naijiria ti ṣe ọpọlọpọ ijamba fun eto ọrọ aje orilẹede yii, ti ko si fun awọn ni anfani lati fẹ fi owo kun owo oṣu awọn osisẹ.

Aarẹ sọ eleyi ninu atẹsita kan ti amugbalegbe rẹ, Femi Adesina fi sita fun awọn akọroyin lọjọ Ẹti, nigba ti Aarẹ gba alejo awọn ẹgbẹ igbinmọ fun awọn osisẹ ijọba ni ile ijọba ni Abuja.

“Mo fẹ ki mo riri ijọba nitori pe nkan ti a dojukọ lọwọ nitori bi ikọlu ṣe waye lọtun lọsi ti ṣe ọpọlọpọ ifasẹyin si orilẹede Naijiria.

aworan Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ osisẹ

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

“Bakana ni a ni idojukọ arun korona jẹ ohun kan to na ijọba ni ọpọlọpọ owo. Ọrọ abo ti gba owo ribiribi ti awọn ika miiran ko ri gba lati bi ọdun meje sẹyin.

“Nitori pe ilu gbọdọ wa ni alaafia ki a to le ni a fẹ bọ si ika miiran

Aarẹ ni saa oun sin sisẹ takuntakun lati ripe awọn mu gbogbo ti awọn iṣe fun ọmọrilẹede Naijiria wa si imusẹ.

“Modupẹ lọwọ awọn osisẹ fun ifọwọsowọpọ pẹlu ijọba mi lati ri pe a ri gbogbo nkan ti a nifẹ lati sẹ, wa si imusẹ.