Ẹ ṣọ́ra o, agbénipajayé kan wà nígboro tó ń pa tọ̀dọ́-tarúgbó báyìí - Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ ṣọra o, agbenigba-jaye kan n bẹ nigboro agbegbe ilu Rẹmọ bayii o to n gbẹmi awọn eeyan bi ẹni gbẹmi adiyẹ o.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti pe agbenipajaye naa yoo dibọn bi ẹni pe ọlọkada loun, bi o ba si ti gbe ẹni to fẹ pa gẹgẹbi ero ni yoo dari ọkada si ibi to dakẹ.
Pupọ awọn to maa n ṣe lọṣẹ jẹ obinrin gẹgẹbi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ.
Arakunrin naa yoo pa irufẹ obinrin to ba gbe bẹẹ lẹyin to ba ti fi ipa baa lopọ tan.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun wa rọ awọn eeyan lati maṣe sun asunpiye o, ki wọn si maa kiyesara bi wọn ba fẹ gun ọkada paapaajulọ ni aṣalẹ.
Awọn ọna iṣọra ti ọlọpaa n la kalẹ
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Abimbọla wa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa paapaa agbegbe Rẹmọ lati maa beere nọmba ibanisọrọ ọlọkada ti wọn ba fẹ gun lalẹ. Ki wọn si tun rii dajọ pe wọn pe nọmba bẹẹ ko dahun lati lee fidi rẹ mulẹ pe kii ṣe arumọjẹ.
O ni eyi yoo lee fun awọn agbofinro ni atọna ninu iwadii wọn.
O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa n sa gbogbo ipa rẹ lati rii daju pe wọn fi oju aṣebi yii han lati jofin laipẹ.












