Ẹ ṣọ́ra fáwọn ajínigbé tí wọ́n n díbọ́n bíi ọlọ́kadà àti awakọ̀ Kórópé nipìnlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, others
Ijọba ipinlẹ Osun ti ṣe ikilọ fun awọn olugbe ipinlẹ lati sọra fun awọn ajinigbe ti wọn n dibọn bii ọlọkada ati awakọ korope lati ṣe ijamba fun awọn eeyan.
Kọmisonna fun eto iroyin ni ipinlẹ naa, Funke Egbemode, lo kede ikilọ fun lọjọbọ ọsẹ yii.
Nigba ti BBC kan si, komiṣọnna yii, Egbemode ni ijọba ipinlẹ Osun kẹfin iroyin nipa bi awọn ajinigbe ṣe n dibọ lati ọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ.
“ Ijọba, pẹlu afọwọsowọpọ awọn ọtẹlẹmuyẹ, ti gbọ pe awọn ọdaran ajinigbe ti darapọ mọ awọn ẹgbẹ oni awakọ ati ọlọkada, ti wọn si ni erongba lati ise ijamba fun awọn araalu to n lo ọlọkada tabi korope ni ipinlẹ Osun.
Kọmisonna wa rọ awọn olugbe ipinlẹ Osun lati yago fun awọn korope ati ọkada ti ko ni ami danimọ ijọba lara.
“ A n pe akiyesi awọn araalu pe ki ṣe ni oju ni alakan fi sọri ti n wọn ba ti fẹ wọ eyikeyi ninu ọkada tabi korope.
Wo imoran ti Funke Egbemode ka kale loruko ijoba:
“Ẹ ma ṣe igbinyanju lati wọ ọkada tabi korope ti ko ni ami ijọba lara.”
“A rọ awọn olugbe ipinlẹ Osun lati kesi awọn ọlọpaa ti n wọn kẹfin iwa ati irisi ajinigbe laadugbo wọn.”
Bakana ni Kọmisọnna ṣe ikilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ lati yago fun irufẹ iwa ti o ba fẹ da alaafia ipinlẹ naa ru.
“Awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ati ọlọkada ni ipinlẹ Osun lati tẹle ofun ati ilana ti ẹka to risi isẹ ati irinajo gbe kale fun wọn.
“Awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn ko gbọdọ fi aye lẹ fun ọmọ ẹgbẹ lati lo iwa jagijagan da eto alaafin ipinlẹ naa ru.
“A ti pe akiyesi awọn ọlọpaa lati fi kun isẹ takunkun ti wọn ṣe lati dabobo awọn araalu.”















