Wó ǹkan ti Ọlọ́pàá sọ̀ lórí òkú èèyàn 20 tí wọ̀n rí nílé Oòsà kan ní Benin

aworan ile osa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo ti ṣorọ lori iṣẹlẹ to waye ni ipinlẹ naa, nibi ti wọn ti ri awọn oku gbigbẹ toto ogun niye ni idi osa kan ni agbegbe Asoro ni opopona Ekunwa ni ipinlẹ Benin.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Chidi Nwabuzor sọ fun BBC News pe o ṣeṣe pe lati ile oku ni wọn ti gbe awọn oku eeyan naa wa nitori pe ami idanimọ wa lara wọn.

“Awọn oku yii ni ami idanimọ lara, eyi ti o fihan pe lati ile oku ni wọn ti gbe wọn wa.”

Ninu awọn oku naa ni wọn ti ri ọkunrin mẹdogun, obinrin mẹta ati awọn ọmọde meji.

Nwabuzor ni awọn eeyan to gbe ni agbegbe lo sawari ile oosa naa, ti wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

O ni awọn ọlọpaa tun sawari awọn ohun etutu bi ẹjẹ ẹranko ati awọn miiran ni ile oosa naa.

Nwabuzor ni ọkan lara awọn afurasi ni ẹni ti o ni ile osa naa ni o jẹ osisẹ ile wosan, nibi ti wọn ti gbe awọn oku naa wa.

O tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ lati sawari arakunrin, ti wọn si tun kan si ile oku ti wọn ti gbe awọn oku naa jade.

Ninu Atẹsita kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita, kọmisonna fun ileeṣẹ ọlọpaa, CP Abutu Yaro ti palasẹ fun igbakẹji kọmisona ileeṣẹ ọlọpaa pe ko bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ naa.