Ṣé òótọ́ lẹ̀sùn tí Adeleke fi kan ìjọba Oyetola pé Ó ń kó owó ìjọba ìbílẹ̀ pamọ́ lọ́nà tí kò bófinmu?

Oríṣun àwòrán, other
Gomina ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan ni ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke tun ti pariwo sita pe oun ti huu nkan gbọ.
O ni oun gbọ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ fun awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ naa lati da ida ọgọrin owo ti wọn ṣẹṣẹ gba lọdọ ijọba apapọ pada si apo ijọba ipinlẹ Ọṣun.
O ni iye owo ti ijọba ibilẹ kọkọkan yoo fi ṣọwọ si aṣuwọn ijọba ipinlẹ Ọṣun yo wa laarin ọgbọn miliọnu naira si miliọnu mẹẹdọgbọn naira.
Ninu atẹjade kan to fi sita, eyi ti alukoro rẹ, Rasheed Ọlawale fi sita, Sẹnetọ Adeleke ni iwa ọdaran gba a ni pe wọn tilẹ tun ni ki awọn ijọba ibilẹ o ko owo naa wa dipo ki wọn san an sinu aṣuwọn.
Bakan naa lo ni aṣẹ ti wọn pa naa sọ pe ko gbọdọ ju ọla lọ o fun wọn lati ko owo naa wa si ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, to wa nilu Oṣogbo.
Sẹnetọ Adeleke to kilọ fun awọn alakoso ijọba ibilẹ naa lati kiyesara pẹlu iwa ọdaran to ni wọn fẹ hu naa,
O wa ṣalaye siwaju sii pe pipaṣẹ fun awọn ijọba ibilẹ lati gba owo ninu aṣuwọn wọn ko wa si ileeṣẹ ijọba ipinlẹ jẹ iwa ọdaran patapata gbaa.
“Gbogbo iwa ati jẹ ipinlẹ Ọṣun run to n lọ lọwọ bayii ni a n ṣe ọfintoto rẹ. Gbogbo oṣiṣẹ ijọba to ba si lọwọ ninu rẹ la o fi kele ofin gbe to ba ya.”
Akitiyan lati kan si agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Ismail Omipindan lori ipe ati atẹjiṣẹ Whatsapp ko tii so eso rere lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.












