Èṣù ti wọnú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP - Bode George

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọkan lara agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oselu People's Democratic Party, Oloye Bode George tí pariwo sìta.
O sorọ lori awuyewuye to n sẹlẹ ninu ẹgbẹ oselu naa, ti o si ni esu tí wọnu ẹgbẹ oselu PDP.
Awuyewuye naa lo ti bẹrẹ lati igba ti igbakeji Aarẹ nigba kan rí, Atiku Abubakar, tí gba asia ẹgbẹ oselu naa gẹgẹ bii oludije sipo aarẹ Orilẹede Naijiria.
Atiku ni igbagbọ wa pe yoo kede Gomina Ipinle Rivers, Nysom Wike, gẹgẹ bi igbakeji rẹ sugbọn ọrọ ba ọna miiran nígba tí Atiku kede Gomina Okowa tí ipinlẹ Delta gẹgẹ igbakeji.
Lati igba naa ni ọpọlọpọ awuyewuye tí bẹrẹ ninu ẹgbẹ oselu naa.
Nigba ti Oloye Bode George n sọrọ lori mohunmaworan kan, o ni ẹgbẹ oselu PDP ni agbara lati yanjú gbogbo awọ to wa ninu ẹgbẹ oselu naa, kí o sì gbajumọ eto ìdibo ọdun 2023.
"O da bí pe esu tí darapọ mọ ẹgbẹ oselu wa ni ṣugbọn mo mọ pe a ni agbara lati yanjú gbogbo awọ to wa laarin wa.
"Ninu ẹgbẹ oselu PDP, a ní ọpọlọpọ awọn eniyan to ni iriri ipa oselu tí yoo pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ jọ lati yanjú awọ to ba.
Ani ọsẹ marun-un lati yanjú gbogbo awọ naa ki a to bẹrẹ ipologo ibo
"Bi a ba ṣe lo agbara wa lati yanju awọn awọ naa ni yoo ṣe afihan pe ẹgbẹ oselu PDP ni idagbasoke ati agbekonle.
Tí a ba kuna lati yanju awọ naa, a ti setan lati borí ibo lọdun 2023.
"Pẹlu iriri mi ninu ẹgbẹ oselu PDP, a ni awọn olori pipe tí yoo yanju awọn rogbodiyan to waye ninu ẹgbẹ oselu People's Democratic Party."















