Ṣé àwọn ikọ̀ aláàbò tí ìjọba ìpínlẹ̀ dá sílẹ̀̀ lè tán ìṣòro ìpèníjà aàbò tí Nàìjíríà ń kojú?

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Nilẹ oni to mọ lorileede Naijiria ipenija aabo jẹ ọkan gbogi ti awọn araalu n koju.
Yala lọwọ awọn janduku agbebọn, adigunjale, ajinigbe tabi awọn ọdaran miran ko fẹ ẹ si ipinlẹ kan ti ko ni ipenija aabo tiẹ to n koju.
Lati dena awọn ipenija aabo wọnyi, awọn ijọba ipinlẹ kan woye ti wọn si da ikọ alaabo ti wọn silẹ yatọ si ọlọpaa to wa labẹ akoso ijọba apapọ.
Laipẹ yi ni ọga awọn ọlọpaa kede pe awọn yoo tẹramọ ipese aabo lawọn ilẹ ẹkọ, ile iwosan ati awọn aaye ohun amayedẹrun mii to jẹ ti ijọba.
Awọn ipinlẹ to ni ikọ alaabo ti wọn da silẹ fun ara wọn

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Mẹta ninu awọn igun orileede Naijiria mefa to wa ni wọn ni ikọ alaabo ti wọn.
Laipẹ yi ipinlẹ Benue to wa ni igun aarin gbungbun ariwa Naijira da ikọ alaabo ti wọn naa silẹ ti Gomina Ortom pe orukọ wọn ni Community Volunteer Guards.
Ni agbegbe yi, ipenija aabo ati ikọlu sawọn araalu jẹ nkan to maa n saba waye.
Gomina si ni awọn ikọ yi ni yoo maa jẹ ipe araalu nigbakugba ti wọn ba n koju ipenija aabo.
Ati awọn ati awọn ọlọpaa to fi mọ awọn ọmọ ogun to n gbe ibọn ni wọn yoo jijọ maa koju ipenija aabo.
Ni iwọ oorun Guusu Naijiria awọn ipinlẹ mẹfẹẹfa to wa nibẹ naa ni ikọ alaabo ti wọn taa n pe ni Amọtẹkun.
Awọn ipinlẹ yi ni :Ekiti, Ondo, Osun, Ogun, Oyo ati Eko.
Ipinlẹ Eko nikan lo dabi ẹni pe awọn ikọ yi ko ti gbera sọ.
Awọn Gomina jijọ ṣe ifilọlẹ ikọ alaabo abẹle yi lati koju ijinigbe ati awọn iwa ọdaran miran.
Lọpọ ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ Amọtẹkun a maa pawọpọ pẹlu awọn alaabo ijọba apapọ to wa nilẹ.
Baa ba tẹsiwaju si awọn ipinlẹ marun un to wa ni ila oorun Guusu Naijiria, awọn ikọ alaabo to wa nibẹ lorukọ wọn n jẹ Ebubeagu.
Ipinlẹ ti wọn ti fẹsẹ rinlẹ ni Abia, Anambra, Enugu, Ebonyi ati Imo.
Gẹgẹ bi tawọn agbegbe mii, idasilẹ Ebubeagu ko ṣẹyin kikoju awọn ikọlu ati ipenija aabo miran ti wọn koju.
Ṣe awọn ikọ alaabo yii le tan iṣoro ipenija aabo?

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Onimọ nipa aabo kan to ba BBC sọrọ, Ben Okezie, sọ pe awọn ikọ alaabo yi ko le da nikan tan iṣoro. aabo.
O sọ pe idasilẹ ọlọpaa abẹle ti ipinlẹ kọọkan ni yoo tan iṣoro yi.
''Ti a ba ni ọlọpaa ni ipinlẹ kọọkan, Gomina yoo le joko pẹlu wọn lati ṣagbekalẹ ọna ti wọn yoo fi ṣeto aabo wọn.''
O fikun pe niṣe lawọn Gomina ipinlẹ maa n lo awọn ikọ alaabo abẹle wọn yi lasiko idibo ki wọn baa le fi koju alatako wọn.
Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn wọnyi ni wọn ma fi n hu iwa janduku lasiko idibo.
O wa gba awọn ile aṣofin agba Naijiria lati wọgile gbogbo awọn alaabo abẹle atifijilante ki wọn si buwọluidasilẹ ọlọpaa ipinlẹ kọọkan.
Kini ijọba apapọ sọ nipa idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Aarẹ Muhammadu Buhari ko faramọ idasilẹ ọlọpaa lawọn ijọba ipinlẹ Naijiria.
''Idasilẹ ọlọpaa ni ijọba ipinlẹ kii ṣe na abayọ''
Esi ti aarẹ fọ ni dahun si ibeere ti akọroyin Channles TV beere lọwọ rẹ ree ni nkan bi oṣu meloo kan ṣẹyin.












