Wo arákùnrin tó fi ọ̀bẹ gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ lójú orun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin Agbẹ kan lorilẹede Ghana ti wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun lẹyin to ge nnkan ọmọ ọkunrin rẹ loju orun.
Arakunrin agbẹ naa, Koffi Atta ṣalaye fun BBC pe ile iwosan loun wa bayii lati gba iwosan.
“Nibayii, mo wa ni ileewosan omi ati abẹrẹ nikan ni wọn n fun mi, ṣugbọn iṣẹ abẹ ni mo nilo.
“Mi o lowo lati ra epo si ọkọ ambulansi ti yoo gbe mi lọ si ile iwosan nla Komfo Anokye Teaching Hospital, KATH fun iṣẹ abẹ.”
Koffi Atta ni nṣe laya oun ja nigba tiu oun ji nigba ti awọn alabagbe oun n sọ pe ẹjẹ n da lara oun.
Nigba to dide lori aga to sun si lo ni oun bẹrẹ si ni ni irora nla ni nnkan ọmọ ọkunrin oun ati koropọn oun.
‘Mo ge nnkan ọmọ ọkunrin mi loju orun’
Arakunrin agbẹ naa ṣalaye fun BBC pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, oun kan ni ki oun sun orun ranpẹ lọsan ọjọ naa lori aga ninu ile oun ni.
“Mo sun sori aga ninu ile. Mo la ala pe mo n ge ẹran kan to wa niwaju mi mi”
Gbogbo rẹ da bi pe loju aye lo ti n ge ẹran to n ge naa.
Ariwo ibosi ara adugbo to ke sita lo mu ki awọn alabagbe rẹ o sa wọle nibi ti wọn ti rii ninu agbara ẹjẹ.
Oun funra rẹ ko mọ nnkan to ṣẹlẹ ni pato. Nigba to gbiyanju ati dide lo to mọ pe nnkan ti ṣe oun nigba to n ni irora lori nnkan ọmọ ọkunrin rẹ.

Oríṣun àwòrán, kofi adjei/adom fm
Igba yi gan an lo tọ mọ pe oun ti ge nnkan ọmọ ọkunrin oun laimọ.
“Mi o ranti igba ti mo mu ọbẹ, o n ṣe ẹmi pẹlu ni kayefi.”
Agbẹ ni Koffi Attah. Ẹni ọdun mẹtadinlaadọta nilagbegbe Assim Akomfode lẹkun aringbungbun orilẹede Ghana.
Bi o tilẹ jẹ pe o ti n gba itọju bayii ni ile iwosan, sibẹ o ni awọn dokita sọ pe iṣẹ abẹ loun yoo nilo.
O ni oun ṣi n la ala oun lọ lẹyin ti oun fi ọbẹ ge nnkan ọmọkunrin oun. Koda o ni oju ala naa loun ti pariwo sita fun aladugbo oun fun iranwọ.
Igba ti awọn aladugbo rẹ gbe e de ile iwosan lo to taji kuro ninu ala to n la naa.
O ṣalaye pe oun ti de ile iwosan tan ki oun to mọ pe oun ti ṣeṣi fi abẹ ge nnkan ọmọkunrin oun loju aye nigba ti oun n la ala pe oun n ge ẹran loju orun.
Ṣiṣe iranran jẹ oun to maa n mu ki eeyan hu awọn iwa aitọ loju orun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣiṣe iranran, ti oyinbo n pe ni Parasomnia jẹ ohun to n mu ki eeyan o maa hu awọn iwa kotọ kan loju orun.
Ko si igba ti eniyan ko lee ṣe iranran loju orun.
Gẹgẹ bi iwe akọsilẹ iroyin aigbadegba lori imọ ilera kan ti akọle rẹ n jẹ Healthline ṣe sọ, ṣiṣe iranran maa n mu ki eniyan maa rin kiri, sọrọ tabi ṣe awọn ohun ti ko bojumu kan loju orun wọn.
Awọn miran layika iru ẹni bẹẹ yoo maa ro pe o ti ji saye ni ṣugbọn to jẹ pe oju orun lo ṣi wa.
Lasiko yii ko si ohunkohun ti iru ẹni bẹẹ baa ṣe ti yoo ranti mọ bo ba ji soju aye.
Sisọrọ loju orun, rinrin kiri loju orun, titọ sile loju orun, ala to n dẹrubani ati awọn nnkan miran wa lara oun to maa n jẹyọ lasiko ti eniyan ba n ṣeranran.












