Pẹ̀lú gbogbo rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà, APC kójú òṣùwọ̀n láti borí ìdìbò 2023- Adamu

Oríṣun àwòrán, Twitter/APCNIGERIA
Alaga fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Sẹnetọ Abdullahi Adamu, ni pẹlu bi eto abo ṣe mẹyẹ lorilẹede Naijiria, ẹgbẹ oṣelu APC koju oṣuwọn lati bori ninu eto idibo lọdun 2023.
Adamu sọ fun BBC News pe ki n ṣe orilẹede Naijiria nikan lo ni ipenija eto abo lọwọlọwọ, o ni gbogbo orilẹele agbaye lo ni ipenija kan tabi meji ti wọn doju kọ.
“Ko ni si aniani pe eto ọrọ ajẹ lorilẹede Naijiria goro si sugbọn ipenija abo jẹ ọkan gbogi to n fa ifasẹyin fun orilẹede Naijiria.
“Bi Naira ṣe fidi rẹmi ni ko ki n ṣe afọwọfa ijọba, ko si orilẹede naa lagbaye ti ko ni ipenija kan atabi meji.”
Adamu tẹsiwaju pe pẹlu gbogbo rogbodiyan naa, ijọba orilẹede Naijria sin ṣe akitiyan lati wa atunse si bi ọrọ abo ṣe mẹyẹ lorilẹede yii.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, Adamu ni ẹgbẹ oṣelu APC ti bẹrẹ isẹ takuntakun lati ri pe wọn bori ninu eto idibo ti yoo waye lọdun 2023, sugbọn o ni ọpọlọpọ idina lo waye fun ẹgbẹ oṣelu lati ma le di ibi ti o lọ.
Awuyewuye lórí Muslim-Muslim Ticket
Sẹnetọ Adamu ni pẹlu bi awuyewuye ṣe n waye lori Muslim-Muslim Ticket ti ẹgbẹ oṣelu APC gbe kalẹ.
O ni oun ni igbagbọ pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria yoo si tẹwọgba aba nitori pe o jẹ ohun ti yoo mu ilọ siwaju ba orilẹede Naijiria.
Adamu ni yoo nira diẹ lati yii ipinnu awọn eeyan pada lorilẹede sugbọn nigba ti o ti jẹ ijọba awarawa ni a ṣe lorilẹede yii, o ni kaluku ni anfani lati ṣe ohun to ba wu wọn.
“Ọlọrun nikan lo le jẹ ki awọn eeyan wa ri pe a nilo agbekalẹ ‘Muslim Muslim Ticket’ fun itẹsiwaju orilẹede Naijiria.
“Lootọ yoo nira lati jẹ ki awọn eeyan nifẹ si nkan ti a gbekalẹ sugbọn a wa yoo gbajumọ bi erongba wa yoo ṣe mu itẹsiwaju ba orilẹede Naijiria.












