Kà nípa àwọn Gomina míì tó tí fi agbára sọ́wọ́ ìgbákejì wọn lásìkò tí wọ́n lọ fún ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́

Awon Gomina

Oríṣun àwòrán, Others

Ka nipa awọn Gomina mii to fi agbara ṣọwọ si igbakeji wọn lasiko ti wọn lọ fun isinmi lẹnu iṣẹ.

Ṣeyi Makinde kọ ni Gomina akọkọ ti yoo fi agbara iṣakoso ṣọwọ igbakeji rẹ lasiko isinmi lẹnu iṣẹ.Kà nípa àwọn Gomina míì tí fi agbára sọ́wọ́ ìgbákejì wọn lásìkò tí wan lọ fún ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́

A ṣe agbeyẹwo awọn Gomina marun mii ti wọn gbe iru igbesẹ naa saaju asiko yii.

1. Nasir El-Rufai - ipinlẹ Kaduna :

Gomina akọkọ ninu iwadii ti a ṣe ni Nasir El-Rufai ti ipinlẹ Kaduna.

O kere tan, El-Rufai ti fi agbara iṣakoso ṣọwọ si igbakeji rẹ lẹẹmeji ọtọọtọ ninu saa akọkọ ati ikeji iṣakoso rẹ.

L'ọdun 2017, Gomina ipinlẹ Kaduna fi ipo rẹ ṣọwọ si igbakeji rẹ, Barnabas Yusuf Bala lasiko ti o rin irinajo lọ si oke okun fun lati lọ kẹkọọ gboye Ọmọwe.

Bala lo n dele gẹgẹ bii Gomina titi ti El-Rufai fi pada de.

Bakan naa l'ọdun 2019, Gomina El-Rufai fi agbara iṣejọba ṣọwọ si igbakeji rẹ, Hadiza Balarabe.

Àkọlé fídíò, Sleep paralysis: Kò sí òkú tàbí aǹjọ̀nú ró n lé ọ lójú oorun- Olajide Obembe

2. Governor Abdullahi Sule - Ipinlẹ Nasarawa

Ninu oṣu ọdun 2020, Gomina Abdullahi Sule ti ipinlẹ Nasarawa rin irinajo lọ si orilẹede Amẹrika fun ayewo ilera.

Ni ibamu pẹlu alakaẹ ofin, Gomina naa fi ọrọ to ile igbimọ aṣofin leti nipa irinajo rẹ ati erongba lati fi agbara iṣakoso ṣọwọ si igbakeji rẹ.

Àkọlé fídíò, Emeritus Ayo Bamgbose: Ibánújẹ́ ni ojú yẹpẹrẹ tí ìjọba fi n wo olùkọ́ báyìí jẹ́ fún mi

3. Babagana Zulum - ipinlẹ Borno

Igbakeji Gomina ipinlẹ Borno, Usman Kadafur ti ṣe akoso ri gẹgẹ bii adele Gomina ipinlẹ naa ninu oṣi kẹrin si ikarun un ọdun 2021, lẹyin ti Gomina Babangida Zulumlọ fun isinmi ọlọjọ mọkanlelogun.

Saaju irinajo naa, Gomina Zulum kọ iwe si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati fi ọrọ to wọn leti gẹgẹ bi ofin ṣe laa kalẹ.

4. Rotimi Akeredolu - Ipinlẹ Ondo

Gomina Rotimi Akeredolu naa ti fi igbakeji tuntun, Lucky Orimisan Aiyedatiwa ṣe adele Gomina lasiko ti a o gba isinmi ọlọjọ meedogun lẹnu iṣẹ.

Àkọlé fídíò, Ìyàwó lè lo ọwọ́ rẹ̀ fi ba ọkọ ṣeré lásìkò Halaada rẹ̀, èyí kò ba ẹ̀sìn jẹ́- Aafa Abdullat

5. Okezie Ikpeazu - Ipinlẹ Abia

Ninu oṣukẹfa ọdun 2020, Gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeazu kede pe oun lugbadi aarun Korona. Lasiko ti o lọ fun igbele, lo kesi igbakeji rẹ, Hon Ude Oko Chukwu lati dele gẹgẹ bii Gomina.

Makinde ati igabkeji re

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde kọwe lati gba isinmi lẹnu isẹ

Seyi Makinde gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, igbákejì rẹ̀ di adelé Gomina

Fun Igba akoko laarin odun mẹta ti o ti n se ijoba ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Seyi Makinde kọ iwe ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lati beere isinmi lẹnu iṣẹ.

Bakan naa sini Makinde ti yọnda agbara fun igbakeji rẹ, Adebayo Lawal lati maa dele gẹgẹ bii gomina, nilana ofin.

Igbesẹ wo ni Makinde gbe ko to bẹrẹ isinmi lẹnu iṣẹ?

Ninu iwe ti Makinde kọ lo ti fi to awọn aṣofin leti wi pe isinmi ti oun fẹ gba yoo waye fun ọgbọn ọjọ, bẹrẹ lati ọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun 2022.

Igbesẹ lati kọ iwe naa lo si da lorii Ipele 190(1) ofin ilẹ wa, ti o kan an nipa fun Gomina lati kọwe si ile igbimọ aṣofin ki o to lọ fun isinmi lẹnu iṣẹ.

Àkọlé fídíò, Àṣà àti èdè Yorùbá dùn púpọ̀, o ní ìtumọ̀ kíkún

Kini Olori ile igbimo Asofin sọ si isinmi naa?

Adari ile igbimọ aṣofin ipinẹ Ọyọ, Debo Ogundoyin fi idi iwe ti Gomina kọ mulẹ pẹlu alaye wipe o tọ ki a gboriyin fun Makinde nitori ifẹ ti o ni si agbegbe Oke-Ogun nipinlẹ Ọyọ lo mu ki o fi agbara iṣejọba ṣọwọ si igbakeji rẹ tuntun ti o wa lati agbegbe naa.

Satide ọjọ kẹta oṣu kẹsan ọdun 2022 ni Makinde pada de sẹnu iṣẹ gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò, Oba Francis Olusola Alao: Agbófinró, Fijilanté àti Amotekun ń gbìyànjú ṣùgbọ́n...