A óò tí gbogbo ìtẹ́ òkú l'Abuja pá, tí ìjọba kó bá sàn ẹ̀tọ́ wá fún wa

Awọn osisẹ to n moju to ayika niluu Abuja ti n dukooko mọ ijọba lati ṣo kọkọrọ si awọn itẹ oku niluu naa, ti ijọba ba kọ lati ma san owo oṣu tuntun ti wọn ṣeleri lati san fun wọn.
Awọn osisẹ naa ni ijọba ti se dehun pẹlu awọn lati 2019, ti wọn si kọ lati mu ileri wọn ṣe.
“A yoo ti itẹ oku Gudu ati Gwanrinpa ti ijọba ba kọ lati san owo oṣu tuntun fun wa ko to di ipari osu kẹsan an.”
“A mọ pe itẹ oku Gudu and Gwarinpa jẹ ohun pataki fun ilu Abuja nitori pe ibẹ ni gbogbo oku awon ti ko ni oluwa maa n wa.”
Olori ẹgbẹ awọn osisẹ to n mojto ayika naa, Mukhtar Bala ni ariwo awọn araalu lo jẹ ki awọn si itẹ oku nigba ti awọn kọkọ bẹrẹ iyansẹlodi naa.
Oludari eto ibi ayika ṣe wa ni amojuto, Onimọẹrọ Osilama Braimah, ni o ti to ni pe ijọba ṣe adehun pẹlu awọn osisẹ to n moju to ayika niluu Abuja lati ọdun 2019.
O ni o ṣeṣe ki wọn lati ma san owo osu tuntun ninu os kẹsan an.
A wa rọ ọmọ ẹgbẹ lati duro di igba naa lati mọ nkan ti ijọba fẹ ṣe.















