Nítòótọ́ ni à máa ṣe 'Stop and Search' sùgbọ́n à kò gbé agbègbè kankan tìpa ni Eko rárá- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko

Komisonna Olopaa Eko

Oríṣun àwòrán, @NPF

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileeṣẹ olọpaa ti ipinlẹ Eko ti fi awọn eeyan lọkan balẹ pe ahesọ lasan ni ọrọ to n jade pe wọn ti gbe enu ibode ipinlẹ Eko ti pa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin to je alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko salaye loju opo twitter rẹ pe ọrọ ko ri bẹẹ.

O ni pe awọn ileeṣẹ iroyin abẹlẹ kan sì kọmisọnna ọlọpaa Alabi gbọ ninu ọrọ rẹ ni.

Hundeyin sọ pe ohun ti Komiṣonna Alabi sọ ni pe awọn agbofinro yoo maa mojuto awọn ẹnubode to wọ ipinle Eko sii ju ti atẹyinwa ni eyi ti ọlọpaa pupọ yoo maa kiyesi loorekoore ki omi ma baa ti eyin wó igbin olugbe ipinle Eko lẹnu.

Alaye wo ni Ileeṣẹ ọlọpaa tun sọ?

Benjamin Hundeyin tun sọ pe wọn yoo maa da awọn eeyan duro loorekoore fun 'Stop and Search' fun ayẹwo pe wọn ko lébọ léru.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Sugbọn kii ṣe pe wọn maa se konile-o-gbele ni ipinle Eko rara.

Bakan naa lo gba gbogbo olugbe Eko nimoran lati maa se oju lalakan fi n sọri ki wọn si maa ṣọra ṣe.