Obasanjo sọ̀rọ̀ lórí àṣà Èmilókan, Ó lulẹ̀

aworan Tinubu ati Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Kehinde Akinyemi

Aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjo sọrọ lori ipade ti oun pẹlu Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni nigba ti o ṣe abẹwo si ile ni ilu Abeokuta .

Nigba ti sọrọ nibi ayẹyẹ igbinmọ to risi yiyan Oba tuntun ti Olowu ti Owu, Oba Saka Metamilola, Obasanjo pe fun fifi ọrọ Emilokan ati O lulẹ sinu Ede Yoruba

O ni; “ Ni bayi, a ti ni awọn ọrọ tuntun sinu Ede Yoruba, Emilokan ati Olule, ọpọlọpọ si ti bẹrẹ si n ma lo wọn.

“Nigba ti mo bi Bola, o rẹrin. Mo ni n jẹ ọrọ to da ida ni, nitori a bẹrẹ sini lo wọn.’”

Lọjọbọ ọsẹ yii ni, Asiwaju Bola Tinubu pẹlu awọn lọbalọba ṣe abẹ si Aarẹ tẹlẹ naa nile rẹ niluu Abeokuta.