Revolution Now: Sowore, Bakare gbé ọga DSS lọ sílé ẹjọ́, wọn ń bèèrè fún bílíọ̀nù kan náírà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore
Omoyele Ṣowore ati Olawale Bakare ti wọn wa latimọle ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti n mugbe bọnu bayii, ti awọn mejeeji si ti gbe ọga DSS, Yusuf Bichi ati ọga ẹka eto idajọ ni Naijiria, Ọgbẹni Abubakar Malami lọ sile ẹjọ.
Ṣowore ati Bakare gbe awọn mejeeji lọ si ile ẹjọ giga l'Abuja, bakan naa ni wọn beere fun ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira fun ẹni kọọkan wọn fun inira ti ajọ DSS fun wọn lati igba ti wọn ti wa latimọle.
Wọn ni owo yii tun wa fun bi ajọ DSS ti fi ẹtọ wọn dun wọn lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ idasilẹ wọn latimọle, ti wọn ko si jẹ kawọn lanfaani si eto ilera, ati ẹtọ awọn lati rin lọ si ibikibi to ba wu awọn.
- Mo bọ́ lọ́wọ́ igbó mímu ṣùgbọ́n ìnira ilé Aafa Ọlọrẹ ti pọ̀jù- ọ̀dọ́ kan
- A jọ ṣe ìyàwó pọ̀, a jọ bímọ ní ọjọ́ kan náà, a tún jọ máa ń ṣàìsàn pọ̀ ni
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Àgbẹdọ̀! Má kọ̀wé fipò sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Yorùbá sọ fún Osinbajo
- Adigunjalè fọ́ báńkì ní Oye Ekiti, wọ́n tún ṣun ọkọ̀ ọlọ́pàá níná
- Àráàlú yarí fún fásitì Babcock fún bo ṣe lé akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn bá lòpọ̀ nínú fídíò
Wọn fikun ọrọ wọn pe mimu ti ajọ DSS mawọn ati iya ti wọn fi jẹ awọn niluu Eko lọjọ keji oṣu kẹjọ ati niluu Oṣogbo lọjọ karun un oṣu kẹjọ tako ẹtọ ọmọniyan awọn.
Awọn agbẹjọro wọn, Femi Falana to pe ẹjọ naa lorukọ Ṣowore ati Bakare, tun ni ọga ajọ DSS ati ti ẹka eto idajọ tun tapa sofin orilẹede Naijiria gẹgẹ bi o ti wa ni akọsilẹ ninu iwe ofin.
Ọjọ kẹfa oṣu kọkanla nile ẹjọ ti paṣẹ pe ki ajọ DSS fi Ṣowore ati Bakare silẹ lahamọ, ṣugbọn DSS kọ eti ikun si aṣẹ ile ẹjọ.








